Ekiti Election: Joe Odumakin ni ko si ìdí fun 30, 000 ọlọpaa

Awọn ọlọpàá
Àkọlé àwòrán,

Ajá ọlọpàá, àwọn ọlọpàá to ń yanju àdó olóro àti àwọn ẹ̀ka míiràn ni yóò péjú síbi ètò ìdìbò náà

Ajafeto araalu kan nilẹ Naijiria, Dokita Joe okei-Odumakin ti koro ojú lori ọgọro ọlọpaa ti wọn ko ṣọwọ si ipinlẹ Ekiti.

Joe okei-Odumakin ni lootọ eto abo jẹ ọkan gboogi lara eroja fun idbo to munadoko, ṣugbọn ko yẹ ko di eyi ti yoo maa mu ikayasoke ba araalu ṣẹlẹ.Ninu ọrọ to ba awọn onwoye kaakiri ti wọn wa lati mojuto bi nnkan ṣe nlọ nibi idibo naa sọrọ nilu Ado Ekiti ni ajafẹtọ naa ti ṣalaye ọrọ yii.

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Ìjọba ìbílẹ̀ làwọn òsìsẹ́ Inec yóó sùn mọ́jú ọjọ́ ìbò

Dokita Odumakin wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lati maṣe ko aya soke, ṣugbọn kiwọn jade lati ṣe ojuuṣe wọn ki wọn si dibo fun oludije ti o ba wu wọn.Bakan naa lo tun rọ awọn oloṣelu lati gba alaafia laaye lasiko idibo naa.

Saaju ọjọ idibo ni Ekiti, Ọ̀gá àgbà àjọ ọlọ́pàá Ibrahim Idris ti fi àwọn ọlọpáà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọn sọwọ́ sí ìpinlẹ̀ Ekiti fún ààbò, to péye nínú ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́jọ́ àbámẹ́ta nípìnlẹ̀ Ekiti.

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Idibo ti bẹrẹ ni pẹrẹwu!

Bakan náà ni ọkọ̀ ofurufu meji ti yóò máa sàmójútó ààbò àti ìgbòkègbodò APC, ọkọ̀ ìjà mẹ́wàá, àti àwọn ọkọ̀ míìràn fun àṣeyori

Lẹ́ka ààbò, ọgọ́run mẹ́tà dín ládọ̀ọ̀ta ni o ti wà ni sẹpẹ́ fún ìgboro Ekiti àti àwọn agbegbe tó dàbí ẹni pe ó nira.