Taa ń láyà tí yóò jẹ ata ní tútù?

Aworan idije ti won ti n je ata tutu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìdíje ata jíjẹ tí n gbálè káàkiri àgbáyé

Gbogbo ẹyìn ọmọ Yorùbá tí ẹ má n lẹnu wí pé ẹ le jẹ ata, è sun mọ ibi láti wá gbọ ìròyìn kayefi yìí.

Lorílè-èdè China èèyàn kan ti gba owó ẹyọ góòlù iwọn giramu mẹta fún pé ọ pegede nínú ìdíje ẹni tó lè yàrá jẹ ata tútù jù.

Lagbegbe Hunan níbi ìdíje ọlodọdun ata jíjẹ ni arakunrin kan Tang Shuaihui ti je ata sonbo àádọta láàrin iṣẹju kàn le diẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀjẹpọ́nnulá fún tòní ti dùn jù, gbìyànjú láti sèé nílé
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni ti ko riran to nlọ'ta ni Mushin

Àwọn olùdíje tó kópa kò sí inú agbami ata ti wọn sì n kò ata jẹ bí ẹni n jobi.

Láti dènà ìṣẹlẹ pajawiri kánkan,wọn tún pèsè àwọn dókítà.

Oúnjẹ wọn lagbegbe Hunan a má ta lẹnu yẹrí yẹrí tí ọ sí wa lára gbajugbaja oúnjẹ ajeponula lorílè-èdè China.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awon ti inu wọn ko gbà jíjẹ ata tútù a má kangun sí ilé ìwòsan

Ọdọọdun ni wọn má n ṣé ajọdun yí tí ọ ma n bẹrẹ losu keje títí di ìparí oṣù kẹjọ.

Ṣùgbọ́n awọn tó n jẹ ata nikan kò lò n ṣé àwọn èèyàn ni kayefi.

Lójú òpó Twitter,faran fídíò oríṣiríṣi nkán arambara ti awọn èèyàn má n je gbòde kan.

Ọkan nínú wọn ní tí arákùnrin kan ti o n jẹ ogun iná

Yato sí ẹni tó n jẹ ina, arákùnrin kàn náà so ara rè di ẹrọ ilota pẹlu bí ọ ti ṣe n fi eyin run igo jẹ nílu Èkó

Ìdíje ata jíjẹ tí n gbálè káàkiri àgbáyé.