Firdaus Amasa di agbẹjọro pẹlú Hijab

Firdaus laarin awọn agba ọjẹ agbẹjọro meji Image copyright Bashir Ahmad
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti ṣe àpèjúwe ìfarajìn Firdaus bíi oun ìwúrí.

Amasa Firdaus, arábìnrin akẹkọ gbọye ìmọ òfin kan tí wọn kò jẹ́ kó bá àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ gbá ìbúra wọ ẹgbẹ́ amòfin tí padà kópa nínú ayẹyẹ igbaniwọle sí ẹgbẹ náà lorílẹ́èdè Nàìjíríà.

Níbi ayẹyẹ igbaniwọle to waye ni Ọjọ Isẹgun ni Abuja, wọn gbà a laye láti kópa nínú ètò igbaniwọle pẹlú ìbòrí Hijab rẹ.

Ti a kò bá gbàgbé ní ọdún 2017, ìgbìmò igbaniwọle ti ṣáájú kọ fun Firdaus láti kópa nínú ayẹyẹ náà pẹ̀lú Hijab rẹ.

Wọn da a pada lẹnu ọnà àti wọ ibùdó ayẹyẹ náà nítorí pé o wọ Hijab.

Gbogbo arọwa pe ki Firdaus bọ́ Hijab re ko si kopa ninu ayẹyẹ naa ja si pabo.

Firdaus kọ̀ láti bọ Hijab rẹ nitori pe ó ni ẹsìn òun lodi sí.

Igbaniwọle rẹ yìí jẹ́ ìṣẹlẹ manigbagbe pàápàá jùlọ fún àwọn agbẹjọro obìrin musulumi ti anfààní ti wa fún bayi lati ma wò Hijab fi kópa nínú ayẹyẹ igbaniwọle sí ẹgbẹ amofin.

Ọpọ àwọn ọmọ orílèèdè Nàìjíríà ló ti n sọ iriwisi wọn lórí ìṣẹlẹ náà.