Dr Bumbum: Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tó ti ń sá, lọwọ́ tẹ̀ ẹ́

Dokita Furtado
Àkọlé àwòrán,

Dokita 'BumBum' ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ olólùfẹ́ lórí Instagram àti Facebook

Ọwọ ti tẹ gbajugbaja onisegun oyinbo to maa n ṣiṣẹ abẹ lati fikun idi awọn obinrin, 'Dokita Bumbum', lẹyin ọjọ mẹrin to ti salọ nigba ti ọkan lara awọn onibaraa rẹ d'oloogbe.

Awọn ọlọpa sọ pe Dokita Denis Furtalo wa ni ahamọ nilu Rio de Janeiro, lẹyin ti aṣiri ibi to sapamọ si tu si wọn lọwọ.

Onibara rẹ ọhun jade laye lẹyin to fun ni awọn abẹrẹ kan lati mu ki idi rẹ tobi si.

Awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu ipaniyan ni wọn fi kan Dokita Furtalo. Bakan naa ni wọn mu iya rẹ, ti wọn si fi ẹsun kan an pe ajọṣe wọn ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn oluwadi ni, Dokita Furtalo ṣe iṣẹ abẹ naa fun Abilekọ Calixto, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta, to tun jẹ iya ọlọmọ meji, ninu ile rẹ (Furtalo) to wa ni Rio de Janeiro, sugbọn o bẹrẹ si ni ṣaisan lasiko ti iṣẹ abẹ naa n lọ lọwọ.

Awọn ọlọpa ni, lẹyin eyi ni Dokita Furtalo gbe e lọ sile iwosan kan, nibi ti ilera rẹ ti doju bolẹ si, to si pada jẹ Ọlọrun nipe lẹyin wakati diẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin ni Brazil sọ pe, eemi obinrin naa ko ja geere nigba to de ileewosan naa.

Ile iwosan Barra D'Or to wa ni ilu Rio de Janeiro, ti dokita naa gbe e lọ, sọ pe, gbogbo igbinyanju lati du ẹmi obinrin naa lo jasi pabo, to si jade laye lowurọ kutu-kutu ọjọ Aiku.

Lẹyin naa ni Dokita Furtalo poora.

Ki lo gbe Abilekọ Calixto de ọdọ rẹ?

Abilekọ Calixto, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta, to tun jẹ iya ọlọmọ meji, ati oṣiṣẹ banki, ni iroyin sọ pe, o rinrinajo kuro nile rẹ to wa ni Cuiaba, to wa laarin gbungbun Brazil, lati lọ ṣe iṣẹ abẹ ti yoo mu ki idi rẹ to bi si lọdọ Dokita Furtado lalẹ ọjọ Abamẹta.

Àkọlé àwòrán,

Iṣẹ́ abẹ kí ìdí le tóbi ni Calixto bá lọ sí ilé 'Dokita BumBum'

Oju wo l'awọn ọmọ Naijiria fi wo iru aṣa idi yiyọ?

Ọpọlọpọ awọn to da si ọrọ lori iṣẹ abẹ ṣiṣe ki idi le tobi si lori Facebook BBC Yoruba gbagbọ pe aini itẹlọrun pẹlu bi Ọlọrun ṣe da awọn to n ṣe e lo mu wọn maa ṣe.

Àkọlé àwòrán,

Pupọ ninu awọn to da fi eero wọn han gbagbọ wipe aini itẹlọrun lo n mu wọn ṣe e

L'Ọjọru ni agbẹjọro Furtado sọ pe, onibaraa oun ko mọ nkan kan nipa iṣẹlẹ naa, ati pe ẹru lo n ba a, ni ko jẹ ko ti yọju s'awọn ọlọpa.

Ninu fidio kan to jade sori ayelujara l'Ọjọbọ, Dokita Furtalo ni 'ijamba to lagbara' ni iku Abilekọ Calixto, nitori pe ẹgbẹrun mẹsan iru iṣẹ abẹ bẹ l'oun ti ṣe lọna to b'ofinmu ni Brazil.

Gbaju-gbaja si ni dokita naa lori tẹlifisan l'orileede Brazil.