IS Global: Oúnjẹ alẹ́ lẹ́yìn aago mẹsan leè fa jẹjẹrẹ

Ounjẹ Image copyright @matsecooks
Àkọlé àwòrán Igbagbọ awọn onimọ ni pe pipẹ ẹ jẹun lalẹ maa n mu ki ara ko wu.

To ba jẹ ọkan lara awọn to maa n pẹ, ko to jẹun alẹ, ajẹ pe o ni lati tun ero ara rẹ pa.

Idi ni pe iwadi kan fihan pe, awọn to maa n jẹun alẹ ki aago mẹsan alẹ to o lu, tabi o kere tan, wakati meji ki wọn to o sun lalẹ, ni anfaani ida ogun, lati maa ni aisan jẹjẹrẹ ọyan ati jẹjẹrẹ ile itọ ọkunrin, ju awọn to maa n jẹun alẹ ti wọn lẹyin aago mẹwa tabi awọn to maa n sun loju ẹsẹ ti wọn jẹun tan.

Iwadi tuntun yii wa lati ọdọ ajọ Barcelona Institute for Global Health (ISGlobal) l'orileede Spain.

Wọn gbe abọ iwadi wọn naa jade ninu iwe apilẹkọ kan ti wọn fi sọri ibaṣepọ to wa laarin asiko ti awọn eniyan n jẹun ati jẹjẹrẹ ọyan pẹ̀lú asetọ̀ fun ọkunrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbajúgbajà òsèré tó tún mọ́ ọbẹ̀ sè

Awọn onimọ ijinlẹ to se iwadi naa, ṣe agbeyẹwo idahun ti awọn eniyan okoo le lẹgbẹta o le ẹyọ kan (621) to ni jẹjẹrẹ ile itọ ọkunrin, ati ẹgbẹrun le nigba ati marun-un (1,205) awọn to ni jẹrẹrẹ ọyan, to fi mọ ọrin le lẹgbẹrin o din mẹjọ (872) ọkunrin, ati ẹgbẹrun kan le ni ọọdunrun (1,205) obinrin ti ko ni jẹjẹrẹ.

Gbogbo wọn lo dahun awọn ibeere ti wọn fun wọn, lori igbe aye wọn, asiko ti wọn n jẹun, bi wọn ṣe n sun, ati awọn nkan mi i.

Àkọlé àwòrán Igbe aye ode oni, ko fi aaye silẹ fun ọpọlọpọ lati tete maa jẹun l'alẹ

Igbagbọ awọn onimọ ni pe pipẹ jẹun lalẹ maa n mu ki ara ko wu, to si maa n mu iyatọ ba iye suga to wa ninu ẹjẹ. Awọn nkan meji yii ni ibaṣepọ pẹlu jẹjẹrẹ.

Agbekalẹ agọ ara eniyan nilo ki eniyan tete jẹun, ki ounjẹ naa si da ki iru ẹni bẹ to sun.

Ṣugbọn, igbe aye ode oni, ko fi aaye silẹ fun ọpọlọpọ lati tete maa jẹun