Ọmọ ọdún mẹrin yìnbon pá ọmọ ọdún méjì ní California

Aworan ọmọde ti o n yin ibon Image copyright Yegor Aleyev

Báwo ló ṣe yín? Níbo lo ti rí ìbon?

Wọn yí láwọn ìbéèrè ti ọ gba ẹnu ará àdúgbò ati awọn ọlọpa ni ìlú California lorílè-èdè Amerika níbi tí ọmọ ọkùnrin ọdún mẹrin kan ti yin ìbon pá ìbátan rẹ tó jẹ ọmọ ọdún méjì.

Ìròyìn ta gbọ ni pé sadede ni awon ọlọpa gba ipe láti ìdílè kan pé ọmọ ọdún méjì kan ti fara gbọta ìbon ti o si n pọkaka ikú.

Àwọn ará àdúgbò so pé n'isẹ ní ìyá ọmọ náà n sunkun nígbà tí àwọn oṣiṣẹ pajawiri n ṣápá láti tọjú ọmọ náà.

Nígbà tí wọn yóò fi gbé dé ilé ìwòsan, àwọn dókítà ní ọ ti je Olohun ni pé.

Awọn ọlọpaati mu Baba baba ọmọ náà Cesar Lopez ti wọn sì ti fi ẹsun kan wí pé o se àkóbá fún ẹmi ọmọdé.

Image copyright STR/AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọlọpaa ti mu Baba omo naa ti o ni ibon to pa ọmọ naa

Wọn ní iwadii ti fí hàn pé baba baba ọmọ náà fi ìbon rẹ sì ìbí tí ọwọ ọmọdé ti le tó.

Ìṣẹlẹ yí ki se akọkọ irú rẹ lorílè-èdè Amerika.