Dókítà t'ọ́mọ kú lọ́wọ́ rẹ̀ bọ́ nínú ẹjọ́ ní Leicester

Dokita Hadiza Bawa-Garba
Àkọlé àwòrán Dokita Hadiza Bawa-Garba gba ìdájọ́ ẹ̀bí lórí ikú ọmọ ọdún mẹ́fa kan ni 2015

Ìdájọ́ padà fojúhàn lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọdún

Dokita ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan to wa ni ilẹ Gẹẹsi ni ile ẹjo ti dajo pe ko jẹbi iku ọmọ odun mefa kan ti wọn fẹsun kan an pe o ṣekupa.

Idajo naa ti ile ẹjọ kotemilọrun fi sọwọ sọ pe ọrọ naa ko jẹmọ ẹsun ti wọn fi kan an ni ọdun 2011.

Lọdun 2015 ni wọn dajo fun un lẹyin igbẹjo pe o jẹbi fifa iku ọmọ ọdun mẹfa kan, Jack Adcock, to ku si ile iwosan Leicester Royal Infirmary nibi to ti n ṣiṣẹ ni 2011.

Iya ọmọ naa, Nicola Adcock, ni ẹjọ naa ko mu inu oun dun rara.

Image copyright Idile Adcock
Àkọlé àwòrán Jack ku si Leicester Royal Infirmary ni 2011

Dokita Hadiza dupe lọwọ awọn alabasisẹ to gbaruku tii nigba igbẹjọ re.

Bakan naa lo tun tọrọ aforijin lọdọ ẹbi ọmọ naa ti o si bawọn kẹdun iku rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDókítà Òbílàdé: Ẹni tó bá lo Tramadol lálòjù leè sùn, kó má jí mọ́

Ọmọde naa, Jack, ni aisan Down syndrome nigba ti wọn gbe e digbagba wa si ile iwosan ti Hadiza ti n sisẹ.

Awọn akẹgbẹ Bawa-Garba to ja fun-un lori ọrọ naa lati igba ti wọn ti da a lẹjọ sapejuwe rẹ gẹgẹ bi dokita akọṣẹmọṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBimpe: Èèyàn bíi tiyín ni àfín, ẹ dẹ́kun dídẹ́yẹsí àfín