Ile ẹjọ Myanmar ran akoroyin Reuters méjì lẹwọn labẹ ofin mẹnumọ

Ile ẹjọ kan lorileede Myanmar ti ran awọn akoroyin ile ise iroyin Reuters meji kan lẹwọn lórí pé wọn n se iwadi lori iwa ipa sise fun awọn eeyan Rohingyas.
Ẹwọn Odun meje leeyan kookan gba.
Lọdun to kọja ni awọn agbofinro mu Wa Lone ati Kyaw Soe Oo fun pe wọn ni iwe ijọba eleyi ti awọn ọlọpa fun wọn.
Awọn mejeeji ni awọn ko mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Olootu agba fun ile ise Iroyin Reuters, Stephen Adler, ni ''ọjọ buruku loni jẹ fun Myanmar,awọn akoroyin mejeeji ati idabo bo awọn akoroyin lagbaye''
Ọpọ eeyan ti se apejuwe ẹjọ naa gẹgẹ bi oun to fọwọkan idaabo bo awọn akoroyin nidi isẹ wọn.