Ilé ẹjọ gíga India dajọ pé ìbálòpọ̀ ọkunrin sí ọkùnrin b'òfin mú

Aworan Okunrin ati Okunrin ti wọn di ara wọn mu ni India

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Òfin to sì lòdì sí ìbálòpọ̀ láàrin ọkùnrin sí ọkùnrin yi ti wa tipe lorílèèdè India

Ilé ẹjọ gíga l'orílẹ̀èdè India ti kede ìdájọ kan to ní ìbálòpọ̀ láàrin ọkùnrin sí ọkùnrin wa ni ìbámu pẹlú òfin orílèèdè náà.

Ìdájọ náà wọgi lè ìdájọ kan to ti kókó ní irú ìwà bẹẹ o lòdì s'ofin labẹ abala 377 òfin ìgbà àwọn amunisin eléyìí tó ká ìbálòpọ̀ láàrin ọkùnrin sí ọkùnrin gẹgẹ bí ẹsẹ.

Òfin yi ti orílèèdè India kọ láti yí padà jẹ ọkan lára àwọn òfin tó ti wa tipe to sì lòdì sí ìbálòpọ̀ láàrin ọkùnrin sí ọkùnrin.

Ṣugbọn lẹnu ọdún bi mélòó kan sẹyìn,àwọn ajafeto-omoniyan ti n ṣé ìpolongo nípa òfin yí tó rí ibasepọ láàrin ọkùnrin sí ọkùnrin gẹgẹ bí ẹsẹ.

Adájọ àgbà Dipak Misra ní ''kò b'ofin mú kí èèyàn fojú ìwà òdaran wo ìbálòpọ̀.''

N'isẹ ní àwọn ajafeto n dunu níwájú ilé ẹjọ ti awọn kan sì bẹrẹ sí ní sunkún ìdùnnú lẹyìn ìkéde ìdájọ náà