Jair Bolsonaro: Ó gbádùn sísọ ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yà-mẹ̀yà, èyí tó ń dá aáwọ̀ sílẹ̀

Aworan Oludije ipo Aarẹ lorileede Brazil Jair Bolsonaro to fajuro lẹyin ti wọn gun lobẹ ni inu

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oludije Aarẹ Jair Bolsonaro fajuro lẹyin ti wọn gun lobẹ ni inu

Oludije kan fun ipo Aarẹ lorileede Brazil, Jair Bolsonaro, ti farapa nigba ti arakunrin kan gun lọbẹ nibi ipolongo idibo .

Aarin ero nibi ipolongo ibo to waye ni ipinlẹ Minas Gerais ni isẹlẹ naa ti waye.

Wọn ti se isẹ abẹ fun oludije naa, ti ireti si wa pe ara rẹ yoo bọ sipo laipẹ.

Oloselu naa, to maa n da awuyewuye silẹ pẹlu ọrọ eleyamẹya to maa n sọ, ti n di ilumọka laarin awọn oludibo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Josh Posh: Inú mi máa ń dùn láti kọrin fún àbúrò mi ní kékeré

Iroyin fi han wi pe, o seese ko rọwọ mu ninu idibo aarẹ losu to n bọ, eyiuu ti Aarẹ ana ni Brazil, Lula da Silva ba kuna nile ẹjọ, lati mu ayipada ba ofin to n ta koo lati kopa ninu idibo naa.

Bawo ni isẹlẹ naa se waye?

Fonran fidio ti o gbode se afihan bi awọn alatilẹyin ti se gbe ọgbẹni Bolsonaro soke lasiko ti wọn gun lọbẹ ni ilu Juiz de Fora .

Lẹyin igba naa lo n ke irora, ti awọn alatilẹyin rẹ si gbe digba-digba wo inu ọkọ.

Ni kiakia ni ọmọ rẹ, Flavio ti sare fi ọrọ sita loju opo Twitter pe, wọn gun baba oun lọbẹ sugbọn ''ko farapa pupọ''.

Ko pẹ sigba naa lo tun salaye sii, nipa bi nnkan se n lọ.

''Ipalara naa pọ ju bi a ti se kọkọ fokansi lọ. O padanu ẹjẹ to pọ. ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun lo wa sugbọn ara rẹ ti n balẹ. Ẹ́ jọwọ, ẹ kun fun adura!''

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Aworan afunrasi ti awọnagbofinro fi sita re

Awọn Dokita to n tọju rẹ ni, lẹyin isẹ abẹ wakati meji ,ara rẹ ti n bọ si sipo pada, sugbọn yoo lo to,o kere tan, ose kan nile iwosan.

Awọn ọlọpa lawọn ti mu afunrasi kan ti orukọ rẹ n jẹ Adelio Obispo de Oliveira.

Se ni awọn alatilẹyin Bolsonaro lu afurasi naa bi ẹni lu bara, nigba ti ọwọ wọn tẹ lẹyin isẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn alatilẹyin Bolsonaro yabo afunrasi Adelio Obispo de Oliveira ti wọn si da bantẹ iya fun.

Iha wo lawọn eeyan kọ si isẹlẹ naa ?

Awọn oludije ti wọn n du ipo pẹlu Bolsonaro ti bẹnu atẹ lu isẹlẹ ohun. Fernando Hada to je wi pe o seese ki o rọpo Lula da Silva ni isẹlẹ naa ''bani lọkan jẹ'

Aarẹ Brazil Michel Temer ni iwa ti ko se faaye gba ni isẹlẹ naa, ti o si gbadura ki ara Bolsonaro tete ya pada.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Awọn alatilẹyin Bolsaro n gbadura ki ara rẹ ya ni kiakia