Egypt rán ènìyàn 700 lọ ẹ̀wọ̀n lórí ìfẹ̀hónúhàn 2013

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn márùndínlọ́gọ́rin ni wọn dajọ iku fun lara awọn to fi ẹhonuhan ni 2013
Orílẹede Egypt ti ran awọn eniyan bii has ẹẹdẹgbẹrin (700) lọri ifẹhonuhan awọn alatilẹyin ẹgbẹ Muslim Brotherhood lẹyin ti wọn le aarẹ orilẹede naa ana Mohammed Morsi kuro lori aleefa ni ọdun 2013.
Ile ẹjọ orilẹede naa tun dajọ iku fun awọn márùndínlọ́gọ́rin bi awọn mẹtadinlaadọta ṣe gba ẹwọn gbere. Ninu wọn ni awọn to jẹ aṣaaju ẹsin.
Ajọ ajafẹtọ Amnesty International ni idajọ naa ko dara nitori pe o lodi si ofin orilẹede naa.
Ọ̀rọ̀ Trump àti Russia kò yàtọ̀ pé àhesọ lásán ni èyí jẹ́
Ẹ o ranti wipe, ifẹhonuhan bẹ silẹ ni orita Rabaa al-Adawiya to wa ni olu ilu orilẹede naa, Cairo, ni 2013, ti awọn agbofinro si pa ọgọrọ awọn eniyan.
Oṣu meloo kan sẹyin ni ile aṣofin Egypt fun awọn alaṣe ẹgbẹ omoogun orilẹede naa ni aabo labẹ ofin fun ẹṣẹ ti wọn ṣẹ nigba ifẹhonuhan naa ati awọn laabi miiran ti wọn ṣe laarin oṣu keje 2013 si oṣu kinni 2016
Oríṣun àwòrán, EPA
Ọpọ̀lọ́pọ̀ ènìyan ni àwọn olóógun yínbọn pa ni oríta Rabaa al-Adawiya ní 2013
Awọn ti wọn ran l'ẹwọn naa ni wọn fi ẹsun idaluru, ipaniyan ati fifa jagidijagan laarin ilu kan.
Ara awọn ti wọn ran l'ẹwọn ni gbajugbaja oniroyin alaworan kan ti orukọ rẹ njẹ Mahmoud Abu Zeid. Ẹwọn ọdun marun ni wọn fun.
Oríṣun àwòrán, EPA
Ẹwọn ọdun marun ni wọn fun gbajugbaja oniroyin alaworan kan ti orukọ rẹ njẹ Mahmoud Abu Zeid.