Ṣé o fẹ́ kí ọpọlọ ọmọ rẹ̀ jì pépé? Jẹ́ kí a kọ ẹ

Aworan ọmọde to n kọ nkan si ori patako Image copyright Anthony Asael/Art in All of Us
Àkọlé àwòrán Abajade iwadi ọdun márùndínláàdọ́ta ni o se afihan yi

Ìwádìí kan fihàn wí pé ó ní àwọn nnkán tí òbí lè ṣe àwọn ọmọ wọn bàa le jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé.

Ni ọdun 1968 ni onimọ ijinlẹ kan ninu imọ ẹkọ Psychometrics, Julian Stanley, ṣe alabapade ọmọ ọdun mejila kan ti o n kọ ẹkọ nipa ẹrọ ayarabiaṣa yunifasiti John Hopkins l'orilẹ-ede Amerika.

Ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Josph Bates mọ iwe daada sugbọn oun ti wọn n kọ ti ṣuu.

Idi ni wi pe imọ to ni ti tayọ tawọn akẹgbẹ rẹ.

Ayẹyẹ ọdún ìbejì dùn, ó lárinrin nílùú Igbó-ọrà

Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa D.O Fágúnwà?

Odọmọde yi jẹ iwuri fun Stanley, ti o si tori rẹ bẹrẹ iwaadi ti o gba a ni ọdun márùndínláàdọ́ta lori idagbasoke awọn ọmọ ọlọpọlọ pipe lara awọn ti a ti ri Mark Zukerberg ti o da Facebook silẹ ati gbajugbaja akọrin, Lady Gaga.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Sergey Brin ti ile iṣẹ́ Google,akọrin Lady Gaga ati Mark Zuckerberg ti Facebook wa lara awọn ọmọ ẹlẹbun to kopa ninu iwadi naa

Ki lo wa pada sẹlẹ si Joseph Bates? O se daada ninu ẹkọ rẹ.

Image copyright LinkedIn
Àkọlé àwòrán Joseph Bates naa ti ṣe iwaadi lọpọlọpọ

O tẹsiwaju pẹlu ẹkọ rẹ, o si gba oye ọmọwe. O bẹrẹ si ni kọ awọn akekọ fasiti, ti o si jẹ ogunna gbongbo ninu awọn to nimọ nipa ẹkọ atọwọda ti a mọ si ''artificial intelligence".

Stanley bẹrẹ eto kan ni yunifasiti ẹka to n moju to awọn ọdọ to ni ẹbun ni ilu Baltimore, eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni ''imọ awọn ọdọ to ja fafa ninu isiro, ti o si se iwadi igbesi aye awọn ọdọ to le ni ẹgbẹrun marun ti wọn pegede.

Nipasẹ iwadi yi ni Stanley ti sọ awọn nnkan pataki to yẹ ki eeyan ṣe ti o ba fẹ ki ọpọlọ ọmọ rẹ ji pepe.

Image copyright Eric Lafforgue/Art in All of Us
Àkọlé àwòrán Akanṣe eto ẹkọ naa a ma fun ọmọ ni anfaani lati tete kuro ni kilasi kan si imi

1) Jẹ ki ọmọ rẹ ni orisirisi iriri

Awọn ọmọ to mọwe daada ṣaba maa n nilo iriri tuntun lati tunbọ sọ ọpọlọ wọn ji.

Ti eeyan ba si aye silẹ fun ọmọ lati ni iriri l'orisirisi,a ma fun ọmọ ni anfaani lati koju ipenija to ba ba pade.

Awọn onimọ ijinlẹ ni lootọ lo dara ki eniyan koju mọ oun to mọ, sugbọn igboya naa se pataki ti ọmọ ba fẹ ṣe nnkan tuntun.

Image copyright Anthony Asael/Art in All of Us
Àkọlé àwòrán O dara ki obi ṣe awari ohun ti ọmọ wọn fẹran, ki wọn si ranwon lọwọ pẹlu rẹ.

2) Ṣe awari ohun ti wọn fẹran ki o si ranwọn lọwọ pẹlu rẹ

Bo ṣe ere idaraya tuntun ni tabi kikopa ninu kilasi ere itage,ti ẹ ba fun awọn ọmọ laaye lati dan nnkan tuntun wo, eyi a ma jẹ ki wọn ni ifarajin lọjọ iwaju.

Ẹ ma ṣe fi ipa mu wọn lati ṣe ohun ti ko wu ọkan wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Jẹ ki ọmọ rẹ se awari ara rẹ

3) Ṣe atilẹyin fun ọmọ rẹ ninu eto ẹkọ rẹ ati awọn ipenija miran to ba n doju kọ.

Ilakaka lati ni imọ sii jẹ atọna lati kọ ẹkọ.

Awọn ọmọde a ma saba bere ibeere ki wọn to bẹrẹ ile ẹkọ. O ṣeeṣe ki o fẹ su ọ sugbọn, o ṣe pataki lati fi suuru ma dahun gbogbo ibeere wọn.

Ọmọ ti ko dakẹ ibeere saba maa n ṣe daada ninu ẹkọ rẹ.

Image copyright Eric Lafforgue/Art in All of Us
Àkọlé àwòrán O dara pupọ ki ọmọde ma bere ibeere, ki obi si maa da a l'ohun.

4)Ku iṣẹ lo n mu ori oniṣẹ ya

Ran awọn ọmọde lọwọ nipa kiki wọn ku isẹ yatọ si mimu abaabọ iṣẹ ni pataki.

Awọn ọmọde a ma wo awokọṣe lara obi wọn.

Ti ọmọ ba n gbiyanju lati kọ ẹkọ, apẹẹrẹ pe yoo ṣe daada ni yi. O si yẹ ki awọn obi maa mu ori wọn wu.

Image copyright Anthony Asael/Art in All of Us
Àkọlé àwòrán Iriri orisirisi se pataki

5)Ijakulẹ kii ṣe ohun ti o gbodọ maa bẹru.

Bi eniyan ko ba ṣina, ko le mọ ọna.

A gbọdọ ri ẹkọ kikọ gẹgẹ bi anfaani lati ran ọmọ lọwọ, ki wọn le mọ bi wọn yoo ti ṣe koju ipenija nigba miran.

Image copyright Frédéric Soltan
Àkọlé àwòrán Awọn obi gbọdo fi ọwọ sowọpọ pẹlu olukọ ọmọ wọn.

6) Ẹ ma fi ọmọ kan we ikeji

Fifi ọmọ we ọmọ a ma mu ipinya wa laarin awọn ọmọde.

Ko da, o le ṣe okunfa ki awọn ọmọ kan ma dunkoko mọ awọn ọmọ miran.

A si tun ma jẹ ki wọn fọkan si pe awọn le ṣe aṣiṣe.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko dara ki a ma fi ọmọ kan yangan niwaju awọn akẹgbẹ rẹ.

7) Ẹ pawọ pọ pẹlu awọn oluko ọmọ yin

Awọn akẹkọ ti wọn loye ati imọ a ma nilo iranwọ ohun elo ẹkọ ti yoo mu wọn peregede, yala lati ọdọ oluko tabi obi wọn.

Pipawọ pọ nipa ṣiṣe amulo eto ẹkọ to wa ni itosi wọn ṣe pataki.

Image copyright Frédéric Soltan
Àkọlé àwòrán Agbajọwọ laa fi sọya lọrọ ẹkọ awọn ọmọ de

8) Ri wi pe o ṣe idanwọ fun ọmọ rẹ lati mọ bo ti ṣe mowe si

Igbesẹ yii le ran obi lọwọ lati beere fun afikun tabi adinku iye iṣẹ ti ọmọ wọn yoo se.

Eleyi si le ranwon lọwọ lati mọ awọn ipenija yowu ti ọmọ wọn ba ni.

Bawo lo sẹ le mọ wi pe ọmọ jẹ ọlọpọlọ pipe?

Wọnyi ni awọn atọna ti yoo jẹ ki o mọ pe ọmọ rẹ ni ẹbun iwe:

• Kii gbagbe nnkan

• Ki ọmọ tete bẹrẹ si ni kawe

• Iru ọmọ bẹẹ yoo yan ere tabi ki o ni imọ ijinlẹ nipa awọn ẹka ẹkọ kan to yatọ si tẹgbẹ rẹ

• Ọmọ rẹ yoo nimọ nipa iselẹ jakejado agbaye

• Ko ni ye ma bere ibeere

• Irufẹ ọmọ bẹ yoo ni ọyaya

• Yoo fẹran orin

•A maa wu ko le iwaju

•A ma ṣe agbekalẹ ọfin tirẹ fun ere idaraya to ba n ṣe