Kí ló yẹ kí ílẹ̀ India se sí ẹkùn tó pa ènìyàn márùń?

India Image copyright Forest department
Àkọlé àwòrán Orílẹ̀èdè India tó ní ẹranko igbó tó pọ̀jù lágbàáyé ń kojú ìsòrò òhún tó yẹ kí wọ́n se láti kojú àwọn ẹranko igbó to n pa àwọn ènìyàn.

Ẹgbẹgbẹrun awọn oṣisẹ eleto aabo lo n wa ẹkun to n kaakiri orilẹede India, lẹyin to ti pa eniyan marun.

Ajọ to n bojuto ọrọ igbo lorilẹede naa ti lo orisirisi ẹrọ igbalode lati wa ẹkun to n sa kiri yii.

Iwadii ti fihan wi pe o ti le ni ọgọrun eniyan to ti padanu ẹmi wọn si awọn ẹranko to ṣekupa wọn, laarin Osu Kẹrin, ọdun 2014 si Osu Karun, ọdun 2017 lorilẹede India to ni ẹkun to poju lagbaye.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kí ló yẹ kí ílẹ̀ India se sí ẹkùn tó pa ènìyàn márùń?

Amọ iwadii ni erin ti pa eniyan bi aadọta le lẹgbẹrun, nigbati ẹkun ti sekupa eniyan mejilelaadọrun.

Iwadii fikun wi pe awọn ẹranko igbo miran naa bi amọtẹkun, kiniun ma n le eniyan lati pa wọn. Ejo ati aja naa ko gbẹyin ninu awọn ẹranko to n sekupa eniyan lọdọọdun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Amọ ẹranko ti awọn eniyan bẹru julọ ni ẹkun.

Awọn ara India fẹ ki ẹkun naa wa laaye

Bi o tilẹ je pe ajọ eleto aabo n gbiyanju lati sawari ẹkun naa, awọn olowo ati gbajumọ to fẹran ẹkun n parọwa si ajo eleto aabo lati ma se pa ẹkun naa.

Àkọlé àwòrán Ni Osu Kẹsan, Ile-ẹjo to gaju ni orilẹede India da ẹjọ to niise pẹlu ki wọn yinbọn pa ẹkun naa nu, eleyii to faye gba ki wọn bẹrẹ si ni wa ẹkun naa pada.

Ajọ naa wa parọwa si awọn eleto aabo lati wa ẹkun naa ri, sugbọn ki wọn gbiyanju lati ma se pa a ayafi to ba wu iwa ipa si wọn lasiko ti wọn ba ri i mu.

Ni Osu Kẹsan, Ile-ẹjo to gaju ni orilẹede India da ẹjọ to niise pẹlu ki wọn yinbọn pa ẹkun naa nu, eleyii to faye gba ki wọn bẹrẹ si ni wa ẹkun naa pada.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan to ju ẹgbẹrunmarundinlaadọta lo fọwọ si lori ẹrọ ayelujara Change.org lati bere fun ki awọn ẹsọ alaabo o mu ẹkun naa laaye, lai pa.

Awọn eniyan to ju ẹgbẹrunmarundinlaadọta lo fọwọ si lori ẹrọ ayelujara Change.org lati beere fun ki awọn ẹsọ alaabo o mu ẹkun naa laaye, lai pa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Amọ awọn eniyan to n gbe ni agbeegbe ti awọn eranko yii pọsi n ran ẹsọ alaabo lọwọ lati le sawari ẹkun naa, ki wọn le fi ni alaafia lagbeegbe naa.

Amọ awọn eniyan to n gbe ni agbeegbe ti awọn eranko yii pọsi n ran ẹsọ alaabo lọwọ lati le sawari ẹkun naa, ki wọn le fi ni alaafia lagbeegbe naa.

Image copyright Forest department
Àkọlé àwòrán Orílẹ̀èdè India tó ní ẹranko igbó tó pọ̀jù lágbàáyé ń kojú ìsòrò òhún tó yẹ kí wọ́n se láti kojú àwọn ẹranko igbó to n pa àwọn ènìyàn.