Canada: Kò sí ẹ̀sẹ̀ nínú igbó mímu àti títà, ẹ tẹ́síwájú

Amugbo Image copyright AFP Contributor

Igbó mímu àti títà ti di gbẹ̀fẹ́ l'orilẹede Canada bayii lai bẹ̀rù agbofinro.

Orilẹede Canada si ni orilẹede keji to tu okun ofin lọrun Kukuye lẹyin ti orilẹ-ede Uruguay ti se bẹẹ.

Ọjà ti wọn ti n ta igbó di ṣiṣi ni oru Ọjọru, bo tilẹ jẹ wi pe awọn araalu ko ti i mọ ipa ti yoo ni lori ilera, ofin ati aabo ilu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈ gbọ àlàyé lẹnu àwọn ti ójúẹlẹgba leko irú iṣẹ ti oògùn olóró má n ṣé lara.

Ọjọ ti pẹ ti awọn to n mu igbo ti fẹ ki wọn ṣọ mimu ati tita rẹ di ohun ti ofin faaye gba.

Agbegbe ati ilu kọọkan ni yoo maa paṣẹ tabi sọ iru igbo ti awọn eniyan yoo maa ta tabi ra ni agbegbe kọọkan.

Ìdí mẹ́rin tí wọ́n fi sọ Gbáná mímu di ìrọ̀rùn ní Canada

  • Olootu ijọba orilẹede naa, Justin Trudeau to tun jẹ olori ẹgbẹ oṣelu Liberal to wa lori aga iṣakoso, ṣeleri pe, oun yoo sọ igbo mimu ati tita di ofin ti wọn ba fi dibo fun oun lasiko to n polongo ibo l'ọdun 2015.
  • Olootu ijọba ọhun nigbagbọ pe ofin atijọ orilẹede Canada to fi ofin de igbo ko ṣiṣẹ, nitori Canada ṣi wa lara awọn orilẹede ti wọn ti n lo igbó julọ pẹlu gbogbo ofin rẹ.
  • O sọ pe ofin tuntun naa ni wọ̀n gbekalẹ lati sọ lilo rẹ di eewọ fun awọn ọmọde, ati lati di ọna mọ awọn janduku, ọdaran to fi n pawo sapo ara wọn.
  • Bakan naa ni ijọba apapọ tun woye pe, irinwo miliọnu dọla ni owo ori ti ijọba yoo maa pa lọdọọdun lara igbó tita.

Kete ti wọn kede pe o ti di lilo ni awọn ile itaja kan ni agbegbe Newfoundland, bẹrẹ si ni ta a ni ọ̀gànjọ́ oru.

Amọ orilẹede South Africa ti sọ igbó lilo di ofin ni ìkọ̀kọ̀.