#Pittsburg shooting: agbófinró gbé afurasí lọ sílé ẹjọ́

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Àwọn ọlọpaa ati akanṣe SWAT di ẹnu ọna Sinagọọgu naa pa

Pittsburg ni ipinlẹ Pennsylvania niṣẹlẹ yii ti wáyé ni orilẹ-ede Amẹrika.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eniyan lo farapa nigba ti afurasi naa da ìbọn bolẹ nile ijọsin Sinagọọgu ti wọn n pe ni Tree of Life lọjọ Abamẹta to kọja.

Awọn agbofinro ni lasiko ti ijọsin Sabbath wọn n lọ lọwọ lo kọju ibọn sawọn olujọsin naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀjọ Ọlọ́pàa Naijiria: A ó fi òsìsẹ́ SARS tó se isẹ́ ibi náà jófin

Ẹsun mọkandinlọgbọn ni wọn fi kan ọkunrin ọmọ ọdun mẹrindinlaadọta yii bii didena ijọsin ati igbagbọ ẹlomii àti ipaniyan.

Oun funra rẹ naa faragbọgbẹ lasiko iṣẹlẹ nla ibi yii.

Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ile Ijọsin Sinagọọgu Tree of Life ni Pittsburg ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ

Awọn olujọsin ṣalaye pe isin akọkọ n lọ lọwọ ni nkan bii aago mẹwaa aaro ni ọkunrin yii wọle to si n yinbọn.

Ọpọlọpọ gba pé eyi jẹ ọkan lara ikọlu sawọn Juu to buru ju lasiko yii.

Bakan naa ni aarẹ Donald Trump to n tukọ Amẹrika ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ ni gbogbo eniyan ri pẹlu ibinujẹ pe iwa yii buru jai lori ikanni rẹ pe:

Awọn agbofinro ṣi n ṣiṣe lọ lori iṣẹlẹ naa ni Pittsburg.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIwode fun Ochanya ti won ba lopo waye nilu Eko