Britain: Ọmọ-ogun 8200 la fẹ́ gbà láti orílẹ̀-èdè Commonwealth

Adinku to ba wọn ọhun ni eyi to ti i buru ju lati ọdun 2010, gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ayẹwo kan sọ Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Adinku to ba wọn ọhun ni eyi to ti i buru ju lati ọdun 2010, gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ayẹwo kan sọ

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti ṣetan lati kede fun awọn eniyan pe, wọn fẹ ẹ bẹrẹ si ni fi iwe pe awọn ọmọ orilẹede mi i lati darapọ mọ ileeṣẹ ologun wọn.

Wọn n reti ki awọn Minisita wọn kede lọjọ Aje, bi eto igbanisiṣẹ ọhun yoo ṣe lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIreti Yusuf: Ìsòro àti fẹjọ́ sùn ló ń mú kí ìwà ìfipábánilòpọ̀ gbilẹ̀ si

Eyi tumọ si pe wọn yoo maa gba awọn eeyan to wa lati orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ́ Commonwealth sẹnu isẹ ologun tiwọn.

Lara awọn orilẹ-ede naa la ti ri - Cameroon, Gambia, Ghana, Malawi, Namibia, Nigeria, Sieraa Leone, South Africa, Tanzania, Zambia, ati awọn orilẹede mi i to wa ni Afrika tawọn naa jẹ ọmọ ẹgbẹ́ Commonwealth.

Bakan naa ni India, Australia, Kenya, Fiji, ati Sri Lanka, ni anfaani lati darapọ mọ ileeṣẹ ologun, koda ti wọn ko ba ti i gbe ni ilẹ Gẹẹsi ri.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ Commonwealth jẹ́ ibaṣepọ awọn orilẹede to ti figba kan wa l'abẹ iṣakoso ilẹ Gẹẹsi

Ṣaaju asiko yii, ohun ti ofin ilẹ Gẹẹsi faaye gba ni pe, ẹni ti i ki ṣe ọmọ orilẹede naa, ṣugbọn to fẹ ẹ darapọ mọ ileeṣẹ ologun wọn, gbọdọ ti gbe ni orilẹede naa fun ọdun maarun.

Ṣugbọn, nitori eto lati gba awọn ọmọ ogun l'ọkunrin ati l'obinrin si ileeṣẹ ologun ori ilẹ, oju ofurufu ati ori omi, lo mu ki ileeṣẹ eto aabo fẹ ẹ yi ofin naa pada.

Aabọ iwadi kan ti wọn gbe jade ni ibẹrẹ ọdun yii fihan pe, ileeṣẹ ẹgbẹrun mẹjọ le igba (8200) ọmọ ogun ni awọn ileeṣẹ ologun naa nilo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'O yé kí ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àti UK dán mọ́rán síi lẹ́yìn àbẹ̀wò May'

Adinku to ba iye ọmọogun to wa ni ilẹ Gẹẹsi ọhun ni eyi to ti i buru ju lati ọdun 2010, gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ayẹwo kan, National Audit Office, ṣe sọ.

Image copyright MOD
Àkọlé àwòrán Awọn ẹṣọ ologun DI Coldstreams gbe asia orilẹede mẹtalelaadọta to jẹ ọmọ ẹgbẹ́ Commonwealth

Gẹgẹ bi iroyin ti iwe iroyin Daily Telegraph to kọkọ gbe iroyin igbanisiṣẹ ọhun sita l'ọjọ Aje ti wi, ileeṣẹ ologun oju ofurufu ati ori omi, yoo bẹrẹ eto igbanisiṣẹ ti wọn loju ẹsẹ, ti ileeṣẹ ologun ori ilẹ yoo si bẹrẹ ti ẹ ni ibẹrẹ ọdun 2019.

Iwe iroyin Telegraph fi kun un pe, awọn ti ki i ṣe ọmọ orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ́ Commonwealth, ko ni le kopa ninu eto igbanisiṣẹ ọhun.