Ayé mà le o! Obìnrin ará Morocco pa olólùfẹ́ rẹ̀, ó fi se ìrẹsì

Ounjẹ kan tí wọ́n pè ní chicken machboos Image copyright Alamy
Àkọlé àwòrán The woman served up her boyfriend's remains in a traditional Emirati dish like this

Obinrin ara Morocco kan ni United Arab Emirates ni wọn ti fi ẹsun kan pe o pa ololufẹ rẹ ti o si se oku rẹ fun awọn oṣiṣẹ ọmọ Pakistan jẹ.

Oṣu mẹta sẹyin ni wọn funra si pe o pa ololufẹ rẹ naa, ṣugbọn aipẹ yuii ni aṣiri rẹ tu nigba ti wọn ba ọkan lara ẹyin ọkunrin naa ninu ẹrọ ilọta igbalode.

Obinrin naa to jẹ ẹni bii ọgbọn ọdun jẹwọ fun ọlọpaa pe, aarẹ ọpọlọ ṣe oun nigba ti oun pa ọkunrin naa ni. Wọn ni yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ.

Iroyin sọ pe ọdun meje ni ifẹ fi wa laarin oun ati ọkunrin naa. Iwe iroyin ilu naa sọ pe arakunrin naa fẹ lọ fẹ ẹlomiran ni o ṣe paa.

Awọn ọlọpaa ko sọ bi o ṣe pa ọkunrin naa, ṣugbọn wọn ni o fi oku ọkunrin naa se irẹsi ti o si fi fun awọn oṣiṣẹ kan ti o wa ni agbegbe naa jẹ

Aburo oloogbe naa to wa sile lati beere rẹ ni o ri eyin rẹ ninu ẹrọ ilọta igbalode ti o si lọ agọ ọlọpaa lati fi ẹjọ sun pe ẹgbọn oun ti di awati.

Iwadii ti wọn ṣe lori eyin naa fi han pe ẹnu oloogbe naa lo ti jade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Wọ́n ní kí n máa jẹ ewébẹ̀ láti dín ìtọ̀ súgà kù'