Ọba Olutayọ: ìgbésẹ̀ Ọọni àti Alaafin ti ń mú ìṣọ̀kàn dé sáàrin àwọn Ọba Yorùbá

Ọba Olutayọ: ìgbésẹ̀ Ọọni àti Alaafin ti ń mú ìṣọ̀kàn dé sáàrin àwọn Ọba Yorùbá

Àsìkò ti tó kí àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá mọ rírì ipò wọ́n.

Ọọniriṣa, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja kejì lo gbalejo awọn lọbalọba ilẹ̀ Yoruba to le ni ọgọrun un nile Ifẹ nibi ojumọ ti n mọ wáyé.

Ninu apero yii ni wọn ti ba ara wọn sọ ootọ ọrọ fodindin ọjọ mẹta gbako lori ìṣọkan ati irẹpọ laarin awọn orí adé lasiko yii.

Oba Micheal Odunayo Ajayi, to jẹ Ẹlẹrinmọ ti Erinmọ Ijeṣa ṣalaye fun BBC Yoruba ohun to n ṣokunfa ìjà laarin awọn ori ade pe, aifagba fẹnikan lo n ṣakoba fún wọn.

Bẹẹ, Kabiesi gba pe, ọmọ baba kan naa dẹ ni gbogbo àwọn.

Ọba Babatunde Agbadẹrọ, to jẹ Onimẹri ti Imẹri naa mẹnuba ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ to wa laarin awọn lọbalọba nigba aye baba nla wọn.

Kabiesi sọrọ lori awọn igbesẹ akọni ti ijoko yii ti ṣetan lati gbe fun idagbasoke iran Yoruba lapapọ bẹrẹ lati ilu ti ẹnikọọkan n jọba le lori.

Ọba Julius Olurọpo Fatanmi, to jẹ Olura ti Ira pẹlu Ọba Dairo Jacob Olutayọ, to jẹ Ọlasọle ti Lasọle gboriyin fún Ọọni ti ile Ifẹ àti Alaafin ti Ọyọ fun ayipada rere to n ṣẹlẹ laarin awọn lọbalọba paapaa lati igba ti Ọjaja kejì ti jẹ nile Ifẹ.

Wọn mẹnuba igbiyanju àwọn agba Ọba yii lati ko awọn ori ade to ku ti àwọn kan ti patì tẹlẹ mọra.

Ọpọlọpọ ọmọ Oodua gba pe didun lọsan iran Yoruba a so leyin apero nla yii paapaa lasiko oselu ni Naijiria nitori ìjọ Ọba ló n jẹ́ ìjọba.