Albert Einstein: 'Ọ̀rọ̀ lọ́kọláya kọjá ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán'

Albert Einstein: 'Ọ̀rọ̀ lọ́kọláya kọjá ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán'

Awọn ẹbí Albert Einstein gbà pé àjẹ́ ni Mileva to jẹ aya rẹ̀.

Albert Einstein gba ami ẹyẹ nobel; prize lọdun 1921 lori imọ sayẹnsi ti wọn n pe ni Physics.

Mileva, aya rẹ jẹ oluranlọwọ pataki si ayanmọ rẹ lati ibẹrẹ aye wọn.

Albert ati Mileva jọ kọkọ n kọ iwe papọ ni ni eyi to fihan pe Mileva mọwe pupọ ti o si maa n ṣalaye nkan miran miran fun Albert.

Awọn tọkọtaya yii jọ ṣe ọpọlọpọ iṣẹ papọ ki ipinya to de si wọn gẹgẹ bii lókọ laya.

Ko pẹ ti wọn kọ ara wọn silẹ ni Albert Einstein gba ami ẹyẹ nobel prize ni eyi ti ọpọ gba pe yoo fun Mileva ninu owó naa.

Wọn jọ fẹnukò pe Mileva naa yoo gba ninu owọ naa tẹle.

Ṣugbọn Albert pada kọ iwe pinpin ogún silẹ ti ko si owó fun Mileva ninu rẹ.

Bi tọkọ taya ti gba ogiri ilé wọn laaye lati lanu silẹ naa ni alangba ti n wọ inu ilé naa.