137 ni iye àwọn obìnrin tí ikú ń pa lójúmọ́ lágbàáyé

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko din ni obinrin mẹ́tàdínlógóje kaakiri agbaye ni awọn ololufẹ wọn tabi mọlẹbi wọn maa n ṣe iku pa wọn lojumọ

Iwadi kan ti ajọ to n ri si ọrọ oogun oloro ati iwa ọdaran ti ṣe afihan wi pe o to obinrin mẹ́tàdínlógóje kaakiri agbaye ni awọn ololufẹ wọn tabi mọlẹbi wọn maa n ṣe iku pa wọn lojumọ.

Iwadi naa ni ''ẹyinkule lọta wa, ile ni aṣeni to n pa ọpọ awọn obinrin wọn yi n gbe.''

O le ni ida meji awọn obinrin ẹgbẹrun lọna mẹ́tàdínláàdọ́rùn ún ti iwadi naa ni lọdun 2017, wọn lugbadi iku lọwọ awọn to sunmọ wọn julọ.

Ninu iye wọn o to ẹgbẹrun lọna ọgbọn ti awọn ololufẹ wọn pa ti awọn ẹgbẹrun lọna ọgun miran si pade ọlọjọ wọn lati owo awọn mọlẹbi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn Obinrin Dahomey: Awọn obinrin ilẹ Afirika ti wọn yii itan pada re e
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObinrin Akansẹ: Ẹsẹ kiku bi ojo kọ mi lati di alagbara
Short presentational grey line

BBC 100 Women fẹ waadi nipa awọn obinrin ti wọn ku wọn yi .A fi oṣu Kẹwa ọdun yi ṣe iwadi awọn iroyin to sọrọ nipa iku awọn obinrin lọjọ kini oṣu naa.A fẹ ṣe alabapin itan awọn obinrin naa pẹlu yin ti a o si ṣe iwadi bi awọn oniroyin ti ṣe kọ nipa awọn iṣẹlẹ wọn yi.

Awọn obinrin le ni idaji awọn to ku lọwọ ololufẹ wọn
Àkọlé àwòrán Awọn obinrin le ni idaji awọn to ma n ku lọwọ ololufẹ wọn

Iku awọn okunrin ṣi pọ ju tobinrin lọ

Iwadi UNODC fi han wi pe ''awọn okunrin wa ninu ẹwu ki awọn ololufẹ wn ṣe iku pa wọn ju awọn obinrin lọ''

Ajọ isọkan orileede agbaye,UN, tọka si wi pe ninu awn eeyan ti wọn ṣe iku pa lagbaye,awọn ọkunrin ko mẹjọ ninu isẹlẹ mẹwa bẹẹ to n waye lojumọ.

Amọ ṣa iwaadi naa kan na lero wi pe o le ni mẹjọ ninu awọn mẹwa to fara kasa iku lọwọ ololufẹ wọn jẹ obinrin.

Iwaadi naa so pe "Iku lati ọwọ ololufẹ ẹni ṣi fi si ọdọ awọn obinrin ju okunrin lọ''

awọn obinrin a ma pade iku wọn lọwọ ololufẹ wọn tabi awọn to sunmọ wọn
Àkọlé àwòrán O ṣeeṣe ki awọn obinrin pade iku wọn lọwọ ololufẹ wọn tabi awọn to sunmọ wọn

Obinrin mẹtadinlaadoọta,lorileede mọkanlelogun lọjọ kan

Iwaadi ajọ isọkan orileede agbaye lọdun 2017 so iroyin to ri gba lati ọdọ awọn ijọba ni ṣoki nipa iṣekupani to n waye.

Wọn ṣe akojọpọ iye awọn obinrin ti wọn pa pẹlu agbelewọn pe awọn iku yi wa l;ati owo ẹni to jẹ ololufẹ tabi mọlẹbi.

BBC 100 Women ati BBC Monitoring ṣe iwadi nipa awọn obinrin ti ọrọ iṣekupani wọn yi kan.

A mojuto bi awọn akoroyin ti ṣe gbe iroyin to ni ṣe pẹlu awọn obinrin ti ẹlomiran pa lọjọ kini oṣu kẹwa ọdun yi kaakiri agbaye.

Awọn akọsẹmọṣẹ waa lagbegbe kọọkanso pe awọn ka obinrin mẹtadinlaadọta ti iku wọn waye nitori pe wọn jẹ obinrin ni orileede mọkanlelogun kaakiri agbaye..

Iwaadi ṣi n lọ lọwọ lori awọn iku wọn yi.

Maarun re ninu awọn iku wọn yi ti awọn akoroyin lagbegbe ti o ti ṣẹlẹ kọkọ gbe jade ti ikọ BBC to wa ni agbegbe naa si fidi wọn mulẹ fun wa.

Judith Chesang Image copyright Family handout
Àkọlé àwòrán Ọkọ Judith lo seku pa sinu oko

Judith Chesang, ọmọ ọdun mejilelogun, lati orileede Kenya

Lọjọ kini Oṣu kẹwa,Judith Chesang ati ọmọ iya rẹ Nancy n ṣiṣẹ ninu oko wọn.

Judith, to jẹ ọlọmọ mẹta , ti ohun ati ọkọ rẹ Laban Kamuren, ṣeṣẹ kọ ara wọn, pada wa si abule awọn obi rẹ to wa ni ariwa orileede Kenya.

Ko pe ti awọn ọmọ iya mejeeji naa bẹrẹ iṣẹ ti ọkọ rẹ ka wọn mọ oko ti o si pa Judith.

Awọn ọlọpa lagbegbe naa ni awọn ara ilu ti ṣeku pa Laban.

obinrin nilẹ Afrika wa ninu ewu lọwọ awọn ololufẹ wọn tabi mọlẹbi
Àkọlé àwòrán Awon obinrin nilẹ Afrika wa ninu ewu lọwọ awọn ololufẹ wọn tabi mọlẹbi

Ilẹ Afrika ni ibi ti iwaadi UN naa sọ wi pe awọn obinrin wa ninu ewu iku lọwọ awọn ololufẹ wọn tabi mọlẹbi wọn.

Eeyan mẹta le ni iwaadi naa ni iru iku bẹ a ma pa laarin awọn eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun.

Ilẹ Asia lo ni iye awọn obinrin ti awọn ololufẹ wọn tabi mọlẹbi pa to poju lọdun 2017 pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun.

Neha Chaudhary Image copyright Manohar Shewale
Àkọlé àwòrán Ọjọ ti Nuha pe ọmọ ọdun mejidinlogun lawọn mọlẹbi rẹ pa

Neha Sharad Chaudury, ọmọ ọdun mejidinlogun lati orileede India

Neha Sharad Chaudury ṣe alabapade iku lọwọ awọn mọlẹbi rẹ lọjọ ti o pe ọmọ ọdun mejidinlogun.

Lọjo ti wọn pa, o jade pẹlu ọrẹkunrin rẹ.

Awọn ọlọpaa fidi ọrọ naa mul wi pe awọn obi rẹ ko fi owo si ibaṣepo rẹ pẹlu ọrẹkunrin rẹ ohun.

Ohun ta gbo ni pe awọn obi rẹ ati awọn ẹgbọn rẹ okunrin ni wọn pa ninu ile wọn nirole ọjọ naa.

Iwaadi ṣi n lọ lori ọrọ naa ti awọn afunrasi ti ọrọ naa kan si wa ni atimọle saaju igba ti igbẹjọ yoo fi waye.

BBC ti gbọ lẹnu agbẹ́joro to n soju awọn obi Neha ati awọn mọlẹbikunrin rẹ wi pe wọn yoo sọ fun adajọ wi pe awọn ko jẹbi ẹsun naa ni.

Aimọye eeyan lo ti pade iku wọn latarui wi pe wọn fẹ ẹni ti awọn mọlbi wn ko lọwọ si.

Akọsilẹ to wa nipa awọn iru iku bayi soro lati ri nitori pe wọn kii mu iru ẹsun bayi wa si ọdọ awọn agbofinro.

Zeinab Sekaanvand Image copyright Private via Amnesty International
Àkọlé àwòrán Aworan Zeinab ti wọn pa ni Iran

Zeinab Sekaanvan, ọmọ ọdun mẹrinlelogun lati orileede Iran

Awọn alaṣẹ Iran lopa Zeinab Sekaanvan lori ẹsun pe o pa ọkọ rẹ.

Wọn bi Zeinab ni ariwa orileede Iran sinu idile talika ti orisun wọn jẹ iran Kurdish.

O sa kuro nile nigba ti o wa ni ọlọmọge pẹlu ireti wi pe yoo ri igbe aye to dun rọrun diẹ.

Ajọ Amnesty International sọ pe ọkọ rẹ maa n fiya jẹ ti o si kọ lati jawe fun ati wi pe awọn ọlọpaa ko ya si ọrọ rẹ.

Wọn mu fun wi pe o pa ọkọ rẹ nigba ti o wa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun

Awọn alatilẹyin rẹ to fi mọ Amnesty International so pe awọn ọlọpaa fi iya jẹ ni titi to fi jẹwọ wi pe o pa ọkọ rẹ .

Iwaadi UNODC naa sọ wi pe awọn obinrin to ba pa ọkọ wọn a ti jẹ iya pupọ lọwọ awọn ọlolufẹ wọn saaju.

Ẹwẹ, awọn iwa ti awọn ọkunrin to ma n ṣe iku pa iyawo wọn lati ri ki wọn ma jowu,tabi ki ẹru ma ba wọn wi pe awọn iyawo wọn yoo fi wọn silẹ.

Iru iwuwasi ba yi lo jọ wi pe a ri apẹrẹ rẹ pẹlu awn lọkọlaya kan ti wọn ri oku wn lọjọ ti Zainab naa ku.

Sandra Lucia Hammer Moura Image copyright Reproduction / Facebook
Àkọlé àwòrán Sandra Lucia Hammer Moura

Sandra Lucia Hammer Moura, ọmọ ọdun mọkandinlogoji lati orileede Brazil

Sandra Lucia Hammer Moura fẹ Augusto Aguiar Ribeiro lẹni ọmọ ọdun mẹrindinlogun.

Awọn mejeeji ti pin ya fun oṣu maarun ki ọkọ rẹ to pa.

Awọn ọlọpaa ni Jardim Taquari fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC wi pẹ wọn gun Sandra lọbẹ lọrun pa ni.

Wọn lawọn ri fọnran fidio kan lori ẹrọ alagbeka ọkọ rẹ nibi ti o ti jẹwọ wi pe oun loun pa iyawo rẹ.

Ninu rẹ o sọ wi pe iyawo rẹ n yan alẹ ti eyi si ba ninu jẹ.

O tun sọ ninu fidio naa wi pe awọn ọlọpaa ko le mu ohun nitori wi pe awọn mejeeji yoo jọ lọ ''pade Ọlọrun pọ ni''

Lẹyin igba naa lo p'okun so ninu iyara ibusun wọn.

Iku Sandra ṣe afihan iṣẹlẹ ki eeyan pa elomiran saaju ki o to pa ara naa

Marie-Amélie Vaillat Image copyright PHOTOPQR/LE PROGRES/Photo Jean-Pierre BALFIN
Àkọlé àwòrán Aworan Marie-Amélie Vaillat

Marie-Amélie Vaillat, ọmọ ọdun mẹrindinlogoji ọmọ ilẹ France

Ọkọ Marie-Amélie,Sébastien Vaillat lo gun ni ọbẹ pa.

Awọn mejeeji ti n gbe lọtọtọ fun ọdun mẹrin ki ọkọ rẹ to pa.

O gun iyawo rẹ lọbẹ ki o to jọwọ ara rẹ fun awọn ọlọpaa.Ọjọ diẹ lyin igba naa ni o pa ara rẹ lẹwọn.

Ni ẹnu ọna ile itaja Marie-Amélie Vaillat ni Rue Bichat,awọn ara adugbo kẹdun pẹlu iwọde.

Iku Marie-Amélie waye lọjọ ti ijọba orileede France ṣe agbejade ofin tuntun lati koju iwa ipa laarin lọkọ laya.

Aworan awọn oluwọde Image copyright PHOTOPQR/LE PROGRES/Photo Jean-Pierre BALFIN
Àkọlé àwòrán Iwọde waye ni iranti Marie-Amélie Vaillat
Short presentational grey line

Kini a le ṣe lati fi iṣẹlẹ pipa obinrin to awọn ijọba leti?

Lati le ṣe akojọpọ awọn itan wn yi,ile iṣẹ BBC lo awọn oṣiṣẹ wọn kaakiri ati awọn amoye lati yẹ iwe iroyin,ori ayelujara kaakiri fun oroyin to ni ṣe pẹlu iṣeku pa awọn obinrin.

Iwaadi naa ṣe afihan iroyin nipa awọn obinrin mẹtadinlaadọta ti wọn ṣeku pa lọjọ kini oṣu kẹwa ọdun 2018.

Di lara awọn ti wọn ku yi ni a fi sọwọ siyin.

Awọn miran ṣi yi wa ti a ko le fidi oun to mu ki wọn pa wọn mulẹ tabi ẹni ti o pa wọn.

Rebecca Skippage lo le iwaju awọn ti o ṣe iwaadi yi ti o si sọ wi pe bi awọn oniroyin ti ṣe gbe iroyin nipa awọn iku wọn yi jade ṣe afihan iha ti awọn eeyan kọ si iru iwa bayi.

Mariam Azwer to n ṣiṣẹ pẹlu BBC ko awọn abajade iwaadi na jọ.

O ni pupo ninu awn iṣẹlẹ iṣekupa awn obinrin ni ko lu sita.O ni eleyi mu ki a beere wi pe kini eeyan gbodo ṣe ''ki awọn akoroyin to mu kikọ iroyin nipa obinrin ni pataki.''

Short presentational grey line

Gbogbo awn aworan ta lo yi la ti fi ofin de lilo wọn

Akoroyin: Krupa Padhy

Olootu: Georgina Pearce

Iwaadi: BBC Monitoring

Iroyin kikọ: Christine Jeavans and Clara Guibourg. Design: Zoe Bartholomew. Development: Alexander Ivanov

Ki ni 100 Women?

BBC 100 Women jẹ ọna ti BBC fi máa n ṣe ayẹsi fun awọn obinrin ti o lamilaaka lagbaye ti a si máa n gbiyanju lati ṣọ itan wọn.

Ọdun yi jẹ eleyi to jẹ ọdun to lamilaaka fun jija fun ẹtọ obinrin. Fun idi eyi, a fẹ fi eto Ọgọrun obinrin 2018 lati fi ta awọn obinrin ji ki wọn si le sọ nipa iriri wọn.

Ẹ kan si wa loju opo ayelujara Facebook, Instagram ati Twitter ki ẹ si lo hashtag #BBC100women