Dókítà ọ̀mùtí ní India se iṣẹ abẹ tó mú ẹmi olóyún àti ọmọ rẹ̀

Aworan Dokita Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko pẹ lẹyin iṣẹ abẹ ti Dokita naa ṣe ti aboyun ohun ati ọmọ rẹ papoda.

Dokita kan ti ko si panpẹ awọn ọlọpaa nipinlẹ Gujarat lorileede India tori pe o m'ọti yo nigba to ṣe iṣẹ abẹ fun aboyun kan.

Ọmọ inu obinrin naa ku ni kete ti o pari iṣẹ abẹ yi ti iya ọlọmọ ọhun naa si gbẹmi mi lẹyin igba diẹ.

Awọn ọlọpaa ni ayẹwọ pẹlu irinṣẹ ṣe afihan wi pe Dokita naa ti mu ọti yo.

Wọn ni awọn n ṣe iwadi lati fidi ọrọ mulẹ boya lootọ ni iku naa ṣẹlẹ latari ọti to mu tabi amuwa Olohun nii.

Dokita PJ Lakhani jẹ agba ọjẹ Dokita ti o ti n ṣiṣẹ fun ọdun mẹẹdogun ni ile iwosan ijọba Sonavala.

Wọn gbe aboyun naa Kamini Chachi wa si ile iwosan to ti n ṣiṣẹ nigba ti o n rọbi.

Awọn akọroyin lagbegbe naa sọ wi pe wọn sọ fun awọn mọlẹbi rẹ to n duro nita wi pe ọmọ ti ku ṣugbọn ẹjẹ n da lara iya.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Obinrin nile iwosan

Eyi mu ki awọn mọlẹbi pamọran pọ lati gbe obinrin naa lọ si ile iwosan mi amọ o ku lọju ọna ki o to de ibẹ.

Awọn ọlọpaa sọ fun BBC Gujarati pẹ Dokita Lakhani pe awọn lori agọ lati ddabo bo ohun nitori pe awọn mọlẹbi obinrin naa le pa ohun.

''A ri wi pe o ti mu oti yo nigba ta de ọdọ rẹ.Nitori naa la fi fi si ahamọ''

Ile iwosan ti ọrọ naa kan ti ṣe agbekalẹ igbimọ kan lati wadi ohun to ṣe okunfa iku iya ati ọmọ naa