COP 24: àwọn olórí orílẹ̀-èdè ṣe ìpàdé ọ̀nà àbáyọ

Image copyright AFP/getty
Àkọlé àwòrán Ona abayọ sori ìṣoro ayipada oju ọjọ gba apero agbaye

Àwọn onimọ nipa ayipada ojú ọjọ́ forikori lori ọna abayọ ati Ìgbẹ́sẹ̀ tuntun to fẹ́ ba ètò inú àyípadà ojú-ọjọ́.

Orilé-ede Poland ni gbogbo awọn eekan lori ipade nipa ayipada oju ọjọ ti pade ki wọn le fẹnuko lori adehun Paris Climate Change 2020.

Gbogbo àwọn to forikori naa gba pe awọn ofin tuntun ti wọn fẹnuko le wọnyii ni yoo mu ẹdinku ba awọn ewu to n de ba igbesẹ ayipada oju ọjọ ni agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption''Ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì n sọnù ni orilẹ̀-ede Burundi'
Image copyright @Jasper junen
Àkọlé àwòrán Ohun to ba ti gba apero ọmọ eriwo kuro ni kekere ni ọrọ yii

Koko to wa ninu adehun Paris naa ni pe ki onikaluku orilẹ-ede kọọkan sa ipa rẹ ki ooru ma mu jù lagbaye ati pe ki koowa maa ṣe nkan to maa mu ooru dinku lagbaye si iwọn meji.

Awọn onimọ kikun nipa oju ọjọ ni ti a ko ba gbe igbésé akin yii, ọpọlọpọ nkan lo maa bajẹ paapaa nilẹ Adulawọ.

Wọn ni ọgbẹlẹ maa wa ni eyi to maa pada bi ìyàn ati ìṣẹ́ lawujọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ayipada ojú ọjọ to ba n mu ooru maa n fa ọ̀gbẹlẹ̀, eyi to maa n bi ìyàn ati ìṣẹ́ lawujọ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCJ Gold: ẹ̀rù kọ́ka ba ìyá mi nígbà ti mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjà jíjà

Aarẹ Mohammadu Buhari ti Naijiria naa wa lara awọn to pesẹ sibi iṣide apero naa. O ni Naijiria ti gbaradi lati rii pe wọn mu ipinnu wọn ṣe lori adehun ti Paris 2020 ọhun.

Bakan naa ni Buhari parọwa fawọn orilẹ-ede to ku lati rii pe wọn mu ofin naa ṣe laarin ọdun diẹ to ku ninu gbendeke naa.

O ni Naijiria ti n sa ipa rẹ lati mu ofin naa ṣe nipa pipese nkan to maa jẹ ki wọn muu ṣẹ lasiko nitori iṣoro ayipada oju ọjọ ni Naijiria ti ri pé o wa lara nkan to n fa ija laarin awọn darandaran ati agbẹ ni ariwa Naijiria .

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOmi titun ti rú nínú oríṣii ètò ìgbéyàwó Yorùbá lásìkò yí