'Tsunami' Indonesia gbẹ̀mí ènìyàn tó lé ní 220

Adúgbò kan tí omí ya bò ní Anyer lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ọjọ́ Abamẹta

Oríṣun àwòrán, Oystein Lund Andersen

Àkọlé àwòrán,

Adúgbò kan tí omí ya bò ní Anyer lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ó ju ènìyàn okòólénígba (220) tó kú nígbà tí òkun ru bo àwọn ìlú bèbè òkún Indonesia lójijì ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Ọ̀kẹ́ àìmoye ni àwọn ilé tí òkun náà TI wọ́ lọ.

Àwọn onímọ̀ ṣàlàyé wí pé Tilẹ̀ tó wà lábẹ́ òkun bá rì ló máa n ṣokunfa òkun ríru náà. Wọ́n tún sọ síwájú pé ọ̀gbún iná inu àpáta tí wọ́n ń pè ní 'Volcano' ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ló fa ilẹ̀ rírì abẹ́ omi ọhun.

Oríṣun àwòrán, Social media

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ olórin 'Seventeen' ń ṣeré lọ́wọ́ nígbà tí òkun ya bò wọ́n

Àwọn àwòrán fi hàn bí òkun náà ṣe ya bo ibi igbáfẹ́ bèbè òkun kan tí ó sì wọ́ àwọn to ń fi orin dá àwọn ènìyàn lárayá.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Àwọn onímọ̀ sọ pé iná inú àpáta ti a mọ̀ sí volcano ni èdè Gẹ̀ẹ́sì lo fa ilè rírì, to jẹ́ ki omi naa ya wọ̀lú

Àwọn alákóso àjọ tó ń kojú ìṣẹ̀lẹ̀ pájáwìrì ni iye àwọn ti àwọn mọ̀ tó ti kú rèé:

  • Agbègbè Pandeglang - 164
  • Agbègbè Serang - 11
  • Agbègbè Gúúsù Lampung - 48
  • AgbègbèTanggamus - 1

Báwo ní ilẹ̀ rírì ṣe ń fa òkun ríru?

Onímọ̀ nípa ọ̀gbun iná inú àpáta (volcano), Jess Phoenix sọ fun BBC pé ti iná inu àpáta bá ti ru jáde nínú ilẹ̀, yoo fọ́ àwọn àpáta sókè, ó sì lè fa ilẹ̀ rírí lábẹ́ òkun, èyí tí yóò wá ya òkun bo ìlú.

Àkọlé àwòrán,

Indonesia padanu ile ati dukia to pọ

Bí iná inu àpáta naá ṣe ru jáde nínú ilẹ̀ rèé.

Oríṣun àwòrán, Oystein Lund Andersen

Àkọlé àwòrán,

Ina riru Anak Krakatoa lọjọ Abamẹta. Photo: 22 December 2018

Tí ẹ bá rántí, oṣù kẹsàn-án, ọdun 2018 ni ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ riri pa ènìyàn to lé ní ẹgbẹ̀rún mejì ní orílẹ̀-èdè náà.

Ni eyi ti inu agbaye bajẹ si ki eleyii to tun ṣẹlẹ lasiko yii.

Oríṣun àwòrán, Gallo Images/Orbital Horizon/Copernicus Sentin

Àkọlé àwòrán,

Ina riru Anak Krakatoa lọjọ Abamẹta. to yọ lati inu ọgbun naa

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Àkọlé fídíò,

Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye