'Boko Haram ló lé mi wá sí Eko tí mo fi di èrò abẹ́ afárá'

'Boko Haram ló lé mi wá sí Eko tí mo fi di èrò abẹ́ afárá'

Ọpọlọpọ lo n sùn nita gbangba loju pópó nipinlẹ Eko

Godwin jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun. O un ati awọn mii ti wọn jọ n sùn ni abẹ afara Eko ba BBC sọrọ lori nkan to gbe wọn de Eko ati nkan ti wọn n là kọja lasiko yii.

Godwin ni oun ko roo ri pe oun maa di ẹni to n sun loju popo ni ipinlẹ Eko nitori wọn ti sọ fun oun pe iṣẹ pọ leko tẹlẹ.

Bẹẹ gẹgẹ ni Ahmed naa sọ pe ogun Boko Haram lo gbe oun de ipinlẹ Eko ti oun ti si di ẹni to n sun abẹ afara.

Iwadii BBc pẹlu awọn to n sùn sabẹ afara ni Eko fihan pé ọpọlọpọ wọn lo n gbiyanju lati te owó ilé jọ ṣugbọn ti ko tii pe lataari ọwọngogo.

Ati pe pupọ wọn lo ṣi ni ireti pe ọjọ ọla a dara ti awọn ba ni iforiti.

Ero wọn ni pe ipinlẹ Eko gba gbogbo eeyan ki wọn to wa.