Wo ọ̀nà márùn ún tí ò lè ràn ọ lọ́wọ́ láti mú u ṣe

Iyipada diẹ diẹ yala ninu ounjẹ le mu iyatọ wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Se awọn iyipada diẹ diẹ ninu igbesi aye rẹ

2019 wole de tan! Asiko ti a ki ara wa kaabọ si ọdun tuntun.

Asiko tun ree fun ọpọlọpo lati ṣe ipinnu ọdun tuntun.

A ma n se apejuwe rẹ gẹgẹ bi 'igba tuntun' fun ẹnikankan wa lati la alakalẹ erongba tuntun fun igbelaruge ara wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Pupọ ninu awọn ipinnu ni o maa n fori sọnpọn amọ lọdun yi o ṣeeṣe ki ti ẹ di mimuṣẹ

O ṣeeṣe ki ti yin niiṣe pẹlu ilera to peye tabi ki ẹ pinnu lati fi owo pa mọ?

Tabi ki ẹ yan ohun ti ẹ fẹran lati maa ṣe tuntun tabi ki ẹ pa eleyi ti ẹ n ṣe tẹlẹ ti?

Oríṣun àwòrán, Nema AAO

Àkọlé àwòrán,

ọpọ n pinnu lati fi iwa miran silẹ

Ohunkohun ti ẹ ba pinnu lati ṣe, ẹ ko le ko iyan ṣiṣẹ koriya (motivation) fun ara wa kere.

Amọ ṣa, gbogbo wa la mọ wi pe ẹnu dun un rofọ.

Ida mẹjọ ninu ida ọgọrun un eeyan ni kii le ṣe ipinnu ọdun tuntun wọn dopin gẹgẹ bi ohun ti iwadii kan ti wọn ṣe ni fasiti Scranton ti Statistic Brain ṣe.

Ṣugbọn eyi ko tumọ si wi pe o yẹ ki o wa lara wọn

Awọn ọna abayọ marun un rèé fun ẹ lati yago fun ijakulẹ ki o si le mu ipinnu rẹ ṣe

Àkọlé fídíò,

Afro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí

1. Ibi pẹlẹbẹ ni ko ti mu

Bi o ba ti sebi o ti ṣe mọ, ati ṣe aṣeyọri rẹ ko ni ṣoro pupọ.

Rachel Weinstein to jẹ onimọ nipa itọsọna ọpọlọ ni ara ipenija ti awọn eeyan maa n ni ni ki wọn ṣeleri ipinnu ti ipa wọn ko ni ka.

Bi o ba ti ti ibi pẹlẹbẹ mu ọlẹ jẹ, ọrọ n yanju bọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ṣe alakalẹ awọn ipinnu ti ko nira saaju. Ti o ba pari wọn, bọ si eleyi to tun nira diẹ

O ni fun apẹẹrẹ ti o ba fẹ pinnu lati maa sare, kọkọ ra bata are sisa ki o si maa sare die die koto di wi pe wa sare onibusọ.

Bo si jẹ ina dida lo fẹyan laayo, kọkọ ran ẹni ti o mọ ina da lọwọ ki o to bọ si iyara idana fun ara rẹ.

Àkọlé fídíò,

Tsunami: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti Jumasil ti sọnù ni wọ́n rii padà

2. Ri wi pe o sọju abẹ niko

A maa n saba la ipinnu kalẹ lalai sọ bi a o ti ṣe muṣẹ.

O ṣe pataki ki a salaye bi a ti ṣe fẹ mu ipinnu wa ṣe

Bi eeyan ba sọ wi pe ''maa ma lọ si ile idaraya lọjọ Iṣẹgun ati ọsan ọjọ A bamẹta''.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ri wi pe o ro ounto fẹ ṣe daada,ibi ti o ti fẹ ṣe ati asiko to fẹ ṣe

O sunwọn ju ki o ni ''maa ma l ile draraya ju bi mo ti ṣe n lọ tẹlẹ lọ''

Alaye ree lati lẹnu ọjọgbọn Neil Levy ti ile ẹkọ fasiti Oxford.

O tẹsiwaju pe ''Bi eeyan ba sọ pato oun to fẹ ṣe,o ṣe anfaani ju ki o ma sọ oju abẹ ni iko lọ''

Àkọlé fídíò,

Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

3. Wa eeyan kun'ra

Ijo ajumọjo san ju aladajo lọ.

Bi o ba ṣe ki o wa ọrẹ kan ti erongba yin papọ, eleyi yoo mu ki o le mu awọn ipinnu rẹ ṣẹ nirọrun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Jijẹ́ ki awọn ẹlọmiran mọ nipa adisọkan rẹ ma n mu ki o rọrun lati tele ipinu

Dokita John Michael ti ile ẹkọ fasiti Warwick ni bi a ba ri awọn ipinnu wa gẹgẹ bi ohun ti yoo lapa lara awọn ẹlọmiran, o ṣeeṣe ki a ri wọn mu ṣe.

Oni bi awn eeyan mi ba ni ipa ti wọn n ko ninu ipinnu wa, yoo rọrun lati mu wọn ṣe.

4. Bibori ijakulẹ

Bi a ba sẹ abapade ipenija, asikoree fun wa lati tun ara wa yewo.

Iru iṣoro wo lo koju?Ọna wo lo le fi koju rẹ daada?Awọnọna abayo wo niko ni ṣiṣẹ?

Ri wi pe o fun ara rẹ ni iwuri ki o si kan sara ti o ba ṣe aṣeyọri kii ba ṣe eleyi to kere.

Awọn iyipada diẹ diẹ le ni ipa to tobi ti o sile tọ ọ si ọna to yẹ

5. Je ki ipinnu rẹ ṣe dede kannaa pẹlu awọn adisọkan rẹ ọlọjọpipẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Adisọkan ati ipinnu nikan ko to

Awọn ipinnu to ṣe anfaani lawọn eleyi tio ba muṣẹ fun igba pipẹ yatọ́ si awọ́n eleyi ti ko lojutu ti wn ko ni ṣe ọ laanfani.

Onimọ, Anne Swinbourne lo n gba wa ni imọran yi.

Ti kii ba sẹ wi pe onifẹ si nkan bi ere idaraya, pipinu lati di gbajugbaja elere idaraya ko le di mimuṣẹ.

Àkọlé fídíò,

Ikorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!

''Awọn to ma n sọ wi pe adisọkan lo ṣe koko a ma saba ni ijakulẹ''

O ni bi o ba ti ri ohun to wu ẹ lọkan, bẹrẹ si ni ṣe pẹlu ilana ti o munadoko.

Bi o ba si ṣe alabapade ipenija kankan, ma ṣe foya lati bere fun iranlọwọ lọdọ awọn eeyan.

Àkọlé fídíò,

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù