Bukola Saraki: Ọmọ alákíkanjú òdì ní ọgá ọlápàá Nàìjíríà

Saraki àti Melaye
Àkọlé àwòrán,

Ọlọ́pàá Nàìjíríà ti dí agbẹnusọ ijọba Buhari

Ààrẹ ilé ìgbimọ aṣòfín Bukola Saraki ti fèsí lóri gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ́ láàrin sẹnátọ Dino Melaye àti àjọ ọlọ̀pàá, ó ni kìí ṣe Dino nikan kọ bíkòṣe pé o lé ṣẹlẹ̀ sẹnikẹ́ni nínú ọmọ Nàìjíríà.

O ní Náìjírìà kìí ṣe Banana Republic, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tó ni kí ọlọ́pàá maaṣe iṣẹ́ wọn nípa dídàabò bo ará ilú àti pípa ofín mọ.

Ẹ̀wẹ̀, wíwá ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yín láti ka ẹ̀sún sí ẹni tí ó ba ni èrò tó yàtọ̀ sí ìjọba tó ń bẹ lóde kò jẹ́ ohun ìtẹ́wọ́ gba rárá

''Ati ń tẹnumọ pípe àwọn elétò ààbò láti yàgò fún dídárí apá kan dá apákan sí nínú isẹ́ wọn"

Àkọlé fídíò,

Tsunami: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti Jumasil ti sọnù ni wọ́n rii padà

Saraki ní àṣà kí a lọ máa wú gbogbo ẹ̀sùn tó ti kọja lójúnà à ti fi àwọn ènìyàn sí àhámọ́ àtí sísọ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò dí aláìlágára tí sọ ọgá àgbà àjọ ọlọ́pàá, Ibrahim Kpotum Idris dí ọmọ ọdọ̀ alákikanju òdì gẹ́gẹ́ bí olóri àjọ ọlọ́pàá tí orílẹ̀-èdè yìí ti ni ri.

Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin fí ẹdùn ọkàn rẹ̀ hàn lórí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ̀, ó fi kú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn jàndùkú inú ẹgbẹ́ APC tó ji ọ̀pá àṣẹ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin gbé lójúkoroju tí gbogbo àgbáyá ń wòólọ́jọ́ si kó rí ìjìyà kankan lẹ́yìn náà.Link

Oríṣun àwòrán, @dinoofficial

Àkọlé àwòrán,

Bukola Saraki: Ọmọ alákíkanjú òdì ní ọgá ọlápàá Nàìjíríà

Ó ní bí ọlọ́pàá ṣe lọ síji bo il'r sẹnatọ Dino Melaye jẹ́ ohun tó mí ìfúnra dáni. Ó fi kún un pé ọkunrin yii kan náà ni wọn ti fi àwọn akaimọye ẹsun kaan tọ sì ń ti àti ilé ẹjọ́ kan bọ́ si ilé ẹjọ́ miran.

Àkọlé fídíò,

Èpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó

Àkọlé fídíò,

Saba Gul: Ọmọbìnrin aláìlápa tí o fẹ̀ dì agbẹjọro