Jolo church attack: Ọpọ èèyàn kú nínú ilé ìjọsìn ní Philippines

Aworan ijamba ti ado oloro meji ṣe fun ile ijọsin katoliki ni Jolo lọjọ kẹtadinlọgbọn osu kini ọdun 2019 Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ibugbamu naa ṣe akoba fun ile ijọsin ohun ni Jolo

Eeyan mẹtadinlọgbọn ti padanu ẹmi wọn nigba ti ado oloro meji dun ni ile ijọsin iya ijọ Katoliki kan ni guusu orileede Philippines.

Awọn alaṣẹ ni ọpọ eeyan farapa ninu iṣẹlẹ ohun.

Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, ibugbamu alakọkọ waye nigba ti wọn n ṣe adura isin niile ijọsin katoliki lagbegbe ibi ti awọn alakatakiti ẹlẹsin musulumi kan wa.

Bi awọn ọmọogun ti ṣe n de ibi iṣẹlẹ naa lati doola ẹmi ni ibugbamukeji waye nibi aye ti awọn eeyan wa ọkọ si.

Ikọlu yi waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn musulumi to pọ lagbegbe naa dibo lati faye gba iṣejọba tara wọn.

Ko ti si ẹnikakan to jade lkati sọ pe awọn lawọn wa nidi iṣẹlẹ naa sugbọn erekusu Jolo la gbọ pe awọn alakatakiti pọ si to fi mọ ikọ kan ti orukọ wọn jẹ Abu Sayyaf

Kini a mọ nipa ikọlu naa?

Awọn alaṣẹ lagbegbe naa sọ pe ibugbamu alakọkọ waye ni nnkan bi ago mẹsan ku iṣẹju mẹẹdogun niile ijọsin Our Lady of Mount Carmel, ibi ti ikọlu ti waye ri tẹlẹ.

Pupọ ninu awọn tofarakasa ninu iṣẹlẹ naa jẹ ara ilu.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọogun wa nikalẹ lagbegbe naa lẹyin ibugbamuohun

Aworan tawọn eeyan fi sọwọ loju opo ayelujara ṣe afihan awọn ọmọogun ti wọn gbe ọkọ ijagun di oju ọna ile ijọsin naa.

Wọn fi ọkọ ofurufu gbe awọn to fara pa lọ si ilu Zamboanga to sunmọ ibi iṣẹlẹ naa.

Minisita eto abo Delfin Lorenzana to ṣe apejuwe iṣẹlẹ ohun gẹgẹ bi iwa to ''buru gba'' rọ awọn ara ilu lati pawọpọ dẹkun iru iwa agbesunmọmi bayi.

''A o ṣa gbogbo ipa lati mu awọn to wa nidi iwa koju ofin''

Ninu idibo bẹnu to waye lagbegbe ohun lai pẹ yi, awọn oludibo faramọ idasilẹ ijọba tiwantiwa fun awọn musulumi to pọ ni guusu Philippines.

Amọ awọn oludibo to wa ni agbegbe Sulu nibi ti erekusu Jolo wa lodi si esi yi.

Awọn alaṣẹ ti saaju fi ireti han pe ibo abẹnu naa yoo mu opin ba ija ọlọjọgbọọrọ to ti n waye laarin awọn musulumi ati ọmọogun orileede Philippine nibi ti awọn ọmọ ijọ katoliki pọ si julọ.

O le ni eeyan ẹgbẹ́run lọna ọgọ́fà to ti ba ikọlu naa lọ.