Ejò bu ìdí obìnrin kan jẹ nínú ilé ìgbọ̀nsẹ

Ẹni to n yọ ejo jade nile igbọnsẹ Image copyright JASMINE ZELENY
Àkọlé àwòrán Onimọ nipa ejo ni wọn pe to wa a ba wọn yọ ọ jade.

Ejo bu arabinrin kan ni ìdí jẹ́ lasiko to fẹ ẹ lo ile igbọnṣẹ kan nile rẹ l'orilẹ-ede Australia.

Gẹgẹ bi nkan ti ẹni to yọ̀ ejo naa jade kuro ninu iho ile igbọnṣẹ naa, Helen Richards to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgọta ti ejo bujẹ fẹ ẹ lo ile igbọnsẹ to wa nile ibatan rẹ kan ni ejo naa yọ ori rẹ sita, to si bu ni idi jẹ.

Ṣugbọn, nitori pe ejo naa jẹ eyi ti ko ni oró lara, wọn kan ba a tọju iho ti ejo lu si lara ni.

Arabinrin Richards sọ fun awọn oniroyin pe, ''mo joko lori awo ile igbọnsẹ ni mo deede ri ti nkan jami jẹ, kia ni mo fo dide t'ohun ti pata mi nilẹẹlẹ, ki n to o ri kinni kan to jọ ijapa, pẹlu ọrun gùn to n sa pada sinu omi.''

Image copyright Jasmine Zeleny
Àkọlé àwòrán Onimọ nipa ejo, Jasmine Zeleny sọ pe omi lo gbe ejo ọhun de inu ile igbọnsẹ naa

Ẹni to mu ejo naa, Jasmine Zeleny sọ pe o wọpọ lati ri ejo ninu ile igbọnsẹ, paapa ni asiko ooru, nitori pe awọn ejo maa n wa omi lasiko naa. O sọ̀ oe ibẹru lo mu ki ejo naa kọlu Arabinrin Richards, nitori pe o di ọna to yẹ ki ejo naa gba jade.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEjo abami to n mu owo ni ajọ Jambu

Iru ejo to bu obinrin naa jẹ, 'Carpet pythons', ko ni oró lara, botilẹ jẹ wi pe awọn onimọ iṣegun oyinbo sọ pe ki iru ẹni bẹ ẹ gba abẹrẹ kokoro tetanus.

Ooru to n mu ni orilẹede Australia bayii pọ de bi pe o ti ṣeku pa ọpọlọpọ ẹṣin, adan ati ẹja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMori ara mi to funfun, mi o mọ pe ẹtẹ ni
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Related Topics