Tani Ọ̀jọ̀gbọ̀n Ayodele Awojobi, onímọ̀ ẹrọ tí o ní kí wọ́n wọgi lè ìbò Ààrẹ Nàìjíríà?

Aworan ọjọgbọn Awojọbi Image copyright Facebook/Greg Nwoko

Lagbo oṣelu Naijiria, ko jẹ tuntun pe ki awọn oloṣelu ma pe fun ifagile ibo paapa eleyi ti esi rẹ ko ba gbe wọn.

Saaju ki awọn oloṣelu ode oni to ma mu igbe yi bẹnu,ni ọjọgbọn onimọ ẹrọ ọmọ kaarọ ojiire kan ti pe fun wiwọgile ibo aarẹ Naijiria lọdun 1983.

Gẹgẹ bi iwoye rẹ, o ni ko si bi iye awọn to forukọsilẹ lati dibo lọdun 1983 to jasi 65,304,818 yoo ṣe ju iye eeyan (57 million) ti ajọ eleto ikaniyan fi sita gẹgẹ bi iye eeyan to wa ni Naijiria lọdun 1963.

Orukọ ọjọgbọn yi a ma jẹ Ayodele Oluwatuminu Awojobi.

Ọjọ kejila Osu kẹta ọdun 1937 ni wọn bi Ayodele Awojobi ladugbo Oshodi nipinlẹ Eko.

Baba rẹ Oloye Daniel Adekoya Awojobi,ọmọ bibi ilu Ikorodu, jẹ oga agba ni ile iṣẹ ọkọ oju irin Nigerian Railway Corporation.

Mama rẹ Comfort Bamidele Awojobi si jẹ onisowo to jẹ ọmọ bibi ilu Modakeke Ile Ifẹ nipinlẹ Osun.

Yoruba bọ, wọn ni ọmọ ti yoo ba ti jẹ aṣamu, ati kekere ni yoo ti ma ṣẹnu ṣamu ṣamu.

Image copyright tundefashola.com
Àkọlé àwòrán Aworan ere Ọjọgbọn Awojobi

Lati kekere ni Ayodele Awojobi ti fakọyọ ninu Eko rẹ ti ko si ye gbegbaoroke ninu gbogbo idanwo ti o ba ṣe.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ni akọsilẹ nipa rẹ, Awojobi pegede ninu Ẹkọ rẹ ti o si jẹ ẹni akọkọ to kere julọ lọjọ ori to gba oye imọ ọjọgbọn lẹka imọ ẹrọ, Professor in Mechanical Engineering, ni yunifasiti ilu Eko lọdun 1974.

O tun jẹ alawọdudu ọmọ ilẹ Afrika akọkọ ti wọn fi oye ọmọwe ninu imọ sayẹnsi Doctor of Science da lọla nile ẹkọ Imperial College of Science and Technology,London ni 1974

Bakanna ni akọsilẹ wa wi pe o leri lati pari ẹkọ ọlọdun mẹrin nipa imọ ẹrọ Bsc Mechanical Engineering laarin ọdun mẹta pere ti o si ṣe bẹ nile Eko fasiti Nigerian College of Arts Science and Technology lọdun 1962.

Image copyright wiki/Babatunde_Fashola
Àkọlé àwòrán Ọgba igbafẹ ti ijọba Gomina Fasola fi sọ orukọ Ọjọgbọn Ayodele ni Yaba

Ayodele Awojobi ko jẹ onimọ lasan bi kii ṣe wi pe o fẹran ki o ma ṣe agbelẹrọ nnkan orisirisi.

Nigba ti o jẹ olukọ ni fasiti ilu Eko,Awojọbi pa ọkọ rẹ ti wọn wa pẹlu ọwọ ọtun pada si eleyi ti wọn wa lati apa osi.

Ko dawọ duro nibe ti o si tẹsiwaju lati ra ọkọ ologun kan ti o yi pada si eleyi ti wọn le dari lọna meji-iwaju ati ẹyin.

Image copyright WIKIPEDIA

Igbesẹ yi mu ki ọkọ na ti o pe orukọ rẹ ni Autonov 1 ni anfaani lati fi ẹyin sare (reverse) laarin iṣẹju perese ju awọn ọkọ miran lọ

O tun ṣe akitiyan pupọ nipa eto ẹkọ ti awọn to ba ranti ko ni gbagbe pe o jẹ atkun eto tanmọ fun awọn akẹkọ lori ẹrọmounmaworan ti wọn pe ni Mastermind.

Image copyright @paadcofficial
Àkọlé àwòrán Ile ẹkọ fasiti ilu Eko ṣe agbekalẹ idije imọ ẹrọ fun awọn akẹkọ fasiti ni iranti Ọjọgbọn Awojobi

Lasiko igbesi aye rẹ, o jẹ alaga igbimọ ile ẹkọ nipinlẹ Eko ti o si kọ ọpọ iwe fun awọn akẹkọ ile iwe girama ati ile ẹkọ giga.

Akitiyan gẹgẹ bi ajafẹtọ ẹni

Awojọbi jẹ eni ti a ma ja fun ohun kohun to ba ni igbagbọ ninu rẹ.

Lọpọ igba lo ti ba ijọba lẹlẹkajẹka wọ ṣokoto kanna lori orisirisi ọrọ to ni ṣe pẹlu iṣejọba.

Awọn to mọ sọ pe o fẹran lati ma para ile ẹjọ ti a si ma bu si ẹkun ti adajọ ba kọ lati da lare ninu ẹjọ.

Igi to tọ kii pẹ ni igbo

Ọjọgbọn Awojobi dagbere fun ye lọjọ aiku ti ṣe ọjọ kẹtalelogun Osu Kẹsan dun 1984 lẹni ọdun mẹtadinlaadọta.

Wọn sin oku rẹ si iboji iku Ikorodu nilu Eko.

Image copyright tundefashola.com
Àkọlé àwòrán Gomina tẹlẹ ri nipinlẹ Eko Babatunde Fashola ati iyawo oloogbe Awojobi,Iyabode Mabel Awojobi nibi ifilọlẹ ọgaba igbafẹ Awojobi Park

O fi iyawo kan saye lọ,iya afin Iyabode Mabel Awojobi ati awọn ọmọ.

Ki lẹda dẹ il fun ẹni to lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: