Àwọn onímọ̀ ṣàwárí 'ihò ìyọ̀ tó gùn jù láyé' nítòsí ìbì tí ìyàwó Lọti inú Bíbélì ti di iyọ̀

Obinrin kan n wo ọwọn iyọ ninu iho Malham Cave ni Israel Image copyright Reuters

Awọn amoye kan lorilẹede Isreal sọ pe awọn ti ṣawari iho inu apata to kun fun iyọ̀ ju lagbaye.

Awọn onimọ naa sọ pe iho ọhun wa nitosi ibi ti Bibeli sọ pe iyawo Lọọti di ọ̀wọ́n iyọ̀ si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẹ̀fọ́ rírò jẹ́ alábárìn iyán, fùfú, ẹ̀bà, àmàlà àti ìrẹsi funfun

Lati bi ọdun meji ni wọn ti ṣe odiwọn iyọ to dipọ to iwọn kilomita mẹwa ninu iho Malham Cave naa, to doju kọ okun Dead Sea.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn onimọ naa sọ, o ṣeeṣe ki iho naa gun si bi òjò ba ṣe n rọ si.

Image copyright Reuters

Ẹwẹ, lati nkan bi ọdun 1980 ni wọn ti ya apa ibikan sọtọ ninu iho naa to gun de ori-oke Sodom, to jẹ apata to gun julọ lorilẹede Israel.

Awari tuntun yii tayọ ọ̀kan to waye lọdun 2006 to ṣafihan iho iyọ Cave of the Three Nudes to wa ni Erekusu Qeshm lorilẹede Iran.

Image copyright Getty Images