Uterus Didelphys - Obìnrin kan bí ibejì lẹ́yìn ọjọ́ 26 tó bí ọmọkùnrin

Ọmọde Image copyright Getty Images

Arabinrin kan ti bi ibeji lẹyin bi oṣu kan to bi ọmọkunrin kan toṣu rẹ ko pe e.

Arifa Sultana, ẹni ogun ọdun bi ọmọ kan ninu oṣu Keji, sugbọn lẹyin ọjọ mẹrindinlọgbọn, ni wọn tun sare gbe digba-digba ls sileewosan nitori pe inu n run un.

Igba ti wọn dele iwosan l'awọn dokita ri i pe oyun ibeji ṣi wa ninu ile ọmọ rẹ keji, eyi si mu ki wọn o ṣiṣẹ abẹ fun.

Inu ilera pipe ni awọn ibeji naa wa laisi wahala kankan.

Àwọn onímọ̀ ṣàwárí 'ihò ìyọ̀ tó gùn jù láyé' nítòsí ìbì tí ìyàwó Lọti inú Bíbélì ti di iyọ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌnú mi kìí dùn nígbà trí mo ń ṣiṣẹ́ ni bánkì tó ìgbà ti mo bẹ̀rẹ̀ mẹkáníìkì

Sultana to wa lati abule kan lorilẹede Bangladesh, lo bi ọmọ rẹ akọkọ si ile iwosan Khulna Medical College ni ẹkùn Khulna.

Gẹgẹ bi Dokita Sheila Poddar to ṣe iṣẹ abẹ fun ṣe sọ, o ni iyalẹnu nla ni ọrọ obinrin naa jẹ fun awọn nileewosan.

O ni 'Sultana ati ọkọ rẹ akuṣẹ, to si jẹ pe ko aworan ayẹwo ko to o bi ọmọ akọkọ.

Bakan naa ni onimọ kan nipa ile ọmọ obinrin l'orilẹede Singapore, sọ pe ile ọmọ meji ni obinrin naa ni - eyi ti awọn onimọ iṣegun oyinbo n pe ni 'uterus didelphys'. Ati pe kii ṣe ohun ti ko wọpọ bi awọn eniyan ṣe lero.

Kini wọn n pe ni uterus didelphys?

Eyi jẹ aiṣedeede inu ara nibi ti obinrin ti maa n ni apo ile ọmọ meji.

Eyi si maa n lagbara debi pe o ma n fa iṣoro airọmọbi.

Dokita Kayode Samuel Adebayo to jẹ onimọ nipa ile ọmọ obinrin ninlu Eko sọ fun BBC pe 'uterus didelphys' ko fi bẹ wọpọ ni Naijiria.

''Iru rẹ meji pere ni mo ti i ri lati bi ọdun mejila ti mo ti n ṣiṣẹ.

Sugbọn ṣaa, fọto aboyun ti owo rẹ ti jawalẹ ti mu ko rọrun fun awn obinrin lati maa mọ ipo ti apo ile ọmọ wọn ba wa.