Kubrat Pulev: Ajẹ̀sẹ́ pàdánù ìwé ìdíje nílùu California nítoríi fífẹnu ko ẹnu akọ̀ròyìn obìnrin

Kubrat Pulev Image copyright Jennifer Ravalo
Àkọlé àwòrán Aworan bi Pulev ti ṣe fẹnuko ẹnu Jennifer

Awọn eleto ẹṣẹ kikan nilu California ti ni ki gbajugbaja ajẹsẹ ọmọ orileede Bulgaria, Kubrat Pulev, lọ rọọkun nile nitori pe o fi ipa fẹnu ko akọrọyin obinrin kan lasiko ifọrọwanilẹnuwo.

Kaakiri oju opo ayelujara ni awọran ibi ti Pulev ti fẹnu ko ẹnu akọroyin ile iṣẹ iroyin Vegas Sports Daily,Jennifer Ravalo ti gbode nigba ti o n bere nipa ija rẹ pẹlu Tyson Fury lọwọ rẹ.

Pulev to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogoji sọ pe orẹ loun ati arabinrin naa ṣugbọn Ravalo ni oun ṣẹṣẹ pada rẹ ni.

Agbẹjọro Ravalo ninu ọrọ rẹ sọ pe iwa naa ko ''bojumu ati pe o lodi si ofin''

Ni bayi,wọn ti paṣẹ ki Pulev farahan niwaju ajọ to n risi ere idaraya nilu California nitori pe wọn ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa.

Ajọ naa sọ pe ki o to le laanfani ati jẹṣẹ ni California, o gbọdọ ''yoju siwaju ajọ naa nibi ti yoo ti fi han pe oun yoo wuwa ni ibamu pẹlu ofin wọn''

Amọ ṣa Pulev ti fi ọrọ sita loju opo Twitter nipa iṣẹlẹ naa.

Image copyright Kubrat Pulev Twitter
Àkọlé àwòrán Pulev fi atẹjade sita loju opo Twitter

Iṣẹlẹ ifipafẹnukọonilẹnu yi waye lẹyin igba ti Pulev na Bogdan Dinu ọmọ orileede Romania ni Costa Mesa nilu California lọjọ abamẹta

Ninu atẹjade kan ti o fi sọwọ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ Ravalo ni ohun ti Pulev ṣe ''doju ti oun'' ti o si ''mu abuku ba oun''

Ravalo salaye pe ''nigba ti a n ṣe ifọrọwanilẹnuwo lo ṣadede bu mi so ti o si fi ipa fẹnuko nu mi.O ba mi lojiji ti mi o si mọ oun ti o yẹ ki n ṣe.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSekinat Quadri ọmọ ọdun meje ajẹsẹ to fẹ dabi Anthony Joshua
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObinrin Akansẹ: Ẹsẹ kiku bi ojo kọ mi lati di alagbara

''Lẹyin igba naa mo rin lọ si ibi ti awọn ẹru mi wa ninu agbepọnyin mi ti o si wa fi ọwọ kan ibadi mi nibẹ naa.Niṣe ni okan rin lọ lalai sọ nnkankan si mi.''

O tẹsiwaju pe ''o mu ki ara mi ko ṣiọ ti mi o si mọ oun ti ma ṣe pe ọgbẹni Pulev lẹ wuwa si mi lọna aitọ.Mi o faramọ bi Pulev ti ṣe fẹnuko mi lẹnu tabi bi o ti ṣe fi ọwọ kan idi mi''

O fi kun pe ko yẹ ki wọn wu iru wa bẹ si obinrin kankan.

Related Topics