UN: Orílẹ̀èdè 170 ló ti fi àjàkálẹ̀ àrun Ẹ̀yi tó wa létí ní 2019

Ọmọde kan to n gba abẹrẹ ajẹsara Image copyright Getty Images

Amọ ajọ isọkan orilẹede agbaye ( United Nations) ti keboosi fun araye pe ajọ eleto ilera lagbaye, WHO ti fi iroyin sita pe, ọwọja arun Ẹ̀yi taa mọ si Measles ti le kankan si ni aarin osu mẹta akọkọ lọdun 2019 pẹlu ida mẹta ju bo se wa ni esin lọ.

UN salaye pe, akọsilẹ ajọ eleto ilera lagbaye fi ye ni pe akirimadalesi ni arun Ẹ̀yi lọdun yii, nitori ko si ẹkun kankan ni awujọ agbaye ti ko fi ọwọba, tabi ba lalejo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ilẹ Afirika agaga, WHO ni ilọpo mẹta ati aabọ (700%) ni ọwọja arun Ẹ̀yi fi le koko si lẹkun naa, pẹlu afikun pe o si seese ki iye ida naa tun lọ soke si, niwọn igba to jẹ pe ida kan ninu ida mẹwa awọn eeyan ti arun yii ba mu ni wọn maa n fi to awọn tọrọ kan leti.

Arun Ẹ̀yi yii ni ajọ UN kede pe o maa n ran ẹlomiran, eyi to si lee se akoba fun ilera agọ ara, ti yoo si nipa lori ọpọlọ ati ọna ọfun.

Image copyright Getty Images

Iroyin naa ni orilẹede Ukraine, Madagascar ati India ni ọwọja arun Ẹ̀yinaa ti mulẹ julọ, ti akọọlẹ si fi han pe ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan lo ti fara kaasa arun yii nibẹ.

Lati osu Kẹsan ọdun 2018, o le ni ẹgbẹrin eeyan to ti jalaisi lati ipasẹ arun Ẹyi ni orilẹede Madagascar nikan.

Bakan naa ni ọwọja arun yii ko da orilẹede Brazil si, to fi mọ Pakistan ati Yemen, "eyi to se okunfa ọpọ iku eeyan, ninu eyi ti ọmọde pọ si", nigba ti iye eeyan to ni arun Ẹyi ni orilẹede Amẹrika ati Thailand naa pọ si, ti wọn si n fi abẹrẹ ajẹsara koju rẹ.

Image copyright PHA

Akọsilẹ ajọ eleto ilera lagbaye naa si fi han pe orilẹede bii aadọsan (170) lo ti ke gbajare sita nipa itankalẹ arun Ẹyi lara awọn eeyan to to ẹgbẹrun lọna mejilelaadọfa ati mẹtalelọgọjọ (112,163) lagbegbe wọn.

Amọ ajọ isọkan orilẹede agbaye ni a lee dena arun ẹyi naa pẹlu abẹrẹ ajẹsara sugbọn akude ti wọ bawọn orilẹede se n gba abẹrẹ ajẹsara naa.