Anger: Onínúfùfù máa ń ní ẹ̀mí gígùn ju Oníwàtútù lọ

Ibinu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lati ọwọ awọn baba nla wa, lati ri ibinu

Ọpọlọpọ awọn eniyan lagbaye ni igbe aye wọn rọrun, ti wọn si n fi ayọ lo igba, amọ kini o fa a, ti ọpọlọpọ eniyan n binu lode oni ju aye atijọ lọ?

Ni igba iwasẹ, awọn eniyan ma n binu fun ọpọlọpọ idi, eleyii ti o ma n mu ki wọn gbiyanju lati jẹ gaba lori ara wọn.

Ọjọgbọn onimọ nipa ihuwasi eda lati fasiti Heidelberg ni Ohio, USA, Aaron Sell ni, awọn eniyan ma n lo ibinu laye atijọ lati fi han wi pe, awọn ni agbara lati paṣẹ, ati lati jẹ ki awọn eniyan gba ọrọ wọn gẹgẹ bi ohun ti o tọna lati se.

Ni igba naa,o ni awọn eniyan ma n lo ibinu ki a le ri wọn gẹgẹ bi ẹni iyi, ti o yẹ ki a bọwọ fun, ati ẹni ti o ma n lo ibinu lati jẹ ki awọn eniyan yi ọkan wọn pada, ati lati jẹ gaba lori awọn eniyan wọn.

Bakan naa ni iwadii oun fihan wi pe, awọn eniyan to n binu laye atijọ ma n ni ẹmi gigun ju awọn ti o tutu niwa ati ise, ti wọn si ma n gba ki awọn onibinu rẹ wọn jẹ.

Ki ni o ma n sẹlẹ si ag ara ti eniyan ba n binu?

Ti eniyan ba n binu lọwọ, gbogbo isan ara onitọun ni yoo ran jade, ti gbogbo ẹya ara eniyan a si setan lati sa asala fun ewu to n bọ, tabi ki o duro lati koju ewu naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Njẹ o le dọrẹ pẹlu awọn eleyii?

Ọpọlọ eniyan a ma a sisẹ bi ago ti o ba n binu nitori wi pe, yoo fi ọkan soju kan lati ri wi pe oun jare gbogbo ọrọ ti oun sọ, eleyi yoo si mu ki o fi gbogbo agbara rẹ sọna kan.

Bakan naa ni ibinu ma n mu gbogbo awọn isan ati orikerike ara, oju ati ẹrẹkẹ gbooro si, ti eniyan a si dabi ni pe ara rẹ pe perepere.

Kini idi ti aye igbalode n jẹ ki awọn eniyan binu fufu?

Ni aye ode oni ti ọpọlọpo eniyan n reti ohun rere lati ọwọ ẹlomiran, pẹlu ero ayelujara ati ọpọlọpọ awọn ohun amayedẹrun to wa ni ikawọ awọn eniyan, ko soro fun eniyan lati ma a se ohun pupọ lẹẹkan naa, eleyii ti o le mu ki eniyan tete ma a binu, ti awọn to ba wa lẹgbẹ rẹ ko ba se ohun to tọ, abi ti o yẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ibinu ma n mu ikunsinu ati asọ dani

Njẹ a ni agbara lori ibinu fufu?

Amọ, awọn ẹlomiran nitori ibinu ma n ba elomiran jijakadi nipa ọrọ ẹnu, tabi ifiyajeniyan tabi isọrọ odi si eniyan lori ẹrọ ayelujara bii Twitter ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Image copyright Getty Images

Onimọ nipa ihuwasi eniyan ati imọ ijinlẹ, Mark Vernon ni, eniyan le lo ibinu fun nkan to dara, ati wi pe o le mu ara ji pepe. Amọ ibinu lọna ti ko dara le ba nkan jẹ, o si lee fa ogun jija, ti awọn agbaagba ni orilẹede kan ba binu sodi lai fi ti awọn ara ilu se.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ki o to binu, ki o to ja... ro o daa da a

Onimọ nipa ihuwasi naa wa rọ awọn eniyan lati ri wi pe wọn lo agbara wọn lori ibinu fufu, nitori ohun ti eniyan lagbara le lori ni, ti ko si yẹ ko lagbara lori eniyan, ki o ma ba a fa wahala tabi laasigbo lawujọ.