Kí ló mú olùdìbò ní India ge ìka rẹ̀ lẹ́yìn tó ṣèṣì dìbò fún ẹgbẹ́ mìíràn?

Pawan Kumar

Oríṣun àwòrán, Yogesh Kumar Singh

Àkọlé àwòrán,

Ogbẹni Kumar ni ọtọ ni ẹgbẹ ti oun dibo yan

Ika to ba ṣe lọba n ge.

Iyẹn fun ẹni to ba ṣ s'ọba. Amọ kini ki a ti wi si ti arakunrin to ge ika ara rẹ nitori pe o ṣeṣi fi ika naa dibo fun ẹgbẹ to yatọ si eleyi to yan laayo.

Ninu fọnran fidio kan ti o ti gbode kan ni arakunrin naa Pawan Kumar ti sọ pe ohun ṣeṣi dibo fun ẹgbẹ to wa lori oye, Bharatiya Janata Party (BJP).

O ni ọtọ ni ẹgbẹ ti ohun fẹ dibo yan ati pe apọju awọn ami idanimọ ẹgbẹ oṣelu lo ko iporuru ọkan ba oun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi eeyan ba ti tẹka tan wọn a ma fi ọda ṣaami si ika na pe ẹni ọhun ti dibo.

''Ẹgbẹ elérin ni mo fẹ tẹka fun ṣugbọn òdòdoóni mo ṣeṣi tẹ ẹ sójú ẹ̀''

O salaye yii ninu fọnran fidio lati fi le ṣe apejuwe ami idanimọ awọn ẹgbẹ to kopa ninu idibo naa.

Lilo ami idanimọ kii ṣe nnkan tuntun ninu ibo orileede India nitori pe wọn a maa fun awọn oludibo lanfaani lati da ẹgbẹ to ba wu wọn mọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eeyan miliọnu 900 ni yoo kopa ninu idibo orileede India

Amọ lọpọ igba ni awọn oludibo maa n koju iṣoro mimọ ami wọn yii nitori pe awọn ẹgbẹ oṣelu a maa dara pọ mọ ara wọn lasiko ibo ti awọn oludibo miiran kan si maa n koju ipenija dida ami wọn mọ.

Ipele meje ni wọn yoo fi ṣe idibo lorileede India eleyii ti wọn ko si ni ọjọbọ.

Ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹrin ni wọn yoo bẹrẹ si ni ka esi ibo.

O le ni eeyan miliọnu 900 to n kopa ninu idibo yii eyi ti o mu u jẹ idibo ti awọn eeyan ti kopa julọ lagbaye.