Ajá dóòlà ọmọ tuntun tí ìyá rẹ̀ bò mọ́lẹ̀ láàyè ni Thailand

Image copyright khaosod
Àkọlé àwòrán Ajá naa bẹrẹ si ni i gbo nigba to ṣakiyesi ẹsẹ̀ ọmọ naa to yọ sita

Ni Ariwa orilẹede Thailand ni Aja kan ti doola ọmọ tuntun jojolo kan lẹyin ti iya ọmọ naa to jẹ ọdọ bo o mọlẹ ni aaye.

Ọmọkunrin naa ni iya rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun, bo mọlẹ ki awọn obi rẹ maa ba a mọ pe o loyun.

Ajá naa ti orukọ rẹ n jẹ Ping Pong lo n gbẹ ilẹ, to si n gbo ni ori papa kan nitosi abule Ban Nong Kham, nigba to ṣakiyesi ẹsẹ ọmọ naa to yọ sita.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionToma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

Ariwo aja yii si lo mu ki olowo rẹ o ṣawari ohun to n mu u gbo, to si ri ẹsẹ̀ ọmọ tuntun naa.

Ni kiakia ni awọn ara abule sare gbe ọmọ naa lọ sileewosan, nibiti awọn dokita ti tọju rẹ, ti wọn si fidirẹmulẹ pe ilera rẹ ṣi wa ni pipe.

Image copyright khaosod
Àkọlé àwòrán Ajá naa, Ping Pong di ẹlẹsẹ kan lẹyin ti ọkọ̀ gba a.

Nibayi, awọn alaṣẹ ti fi ẹsun pipa ọmọ ti, ati igbiyanju lati ṣekupani kan iya ọmọ naa nile ẹjọ.

Panuwat Puttakam to jẹ ọlọpaa nileesẹ ọlọpaa Chum Phuang sọ fun iwe iroyin Bangkok Psot pe iya ọmọ naa ti wa ni abẹ amojuto awọn obi rẹ ati onimọ nipa ihuwasi ẹda.

O fikun un pe ọmọbinrin naa kabamọ iwa to hu. Awọn obi rẹ naa si ti pinnu lati tọju ọmọ tuntun ọhun.

Related Topics