Aviation Strike: Ẹ̀gbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfurufú bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Ọkọ baalu Image copyright OTHER
Àkọlé àwòrán Ọkọ baalu

Awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu yoo gun le iyanṣẹlodi lonii ọjọru ọjọ kejilelogun oṣu karun.

Wọn gbe igbesẹ yii latari pe wọn ni ijọba ko ṣe ohun to yẹ fun awọn lẹyin ti wọn fun ijọba ni gbedeke ọjọ meje ki wn to gun le iyanṣẹlodi naa.

Àwọn òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfúrufú MMA2 ṣẹ́welé ìyansẹ́lódì

Òṣìṣẹ́ ẹka arinrinajo ọkọ̀ òfúrufú Nàìjíríà fagilé ìyanṣẹ́lódì

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn òṣìṣẹ́ pápápọ̀ òfurufú ní Ìpínlẹ̀ Eko fi ẹ̀honú wọn hàn

Awọn oṣiṣẹ ń bere fun ki ijọba ṣe agbekalẹ igbimọ awọn oṣiṣẹ ijọba ti ile iṣẹ irina ofurufu atawọn nkan mii ti wọn n bere.

Musa Diru to jẹ alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile iṣ irina ofurufu (NUATE) ni ipinlẹ Eko sọ fun BBC pe awọn oṣiṣẹ awọn ko ni lọ ibi iṣẹ lati ọjọru titi ijọba yoo fi da wọn lohun.

Tinubu gbéra lọ odidi Mecca láti lọ ṣàbòsí - PDP

Ìdí tí a fi ṣe òfin tuntun fún àwọn akọ̀ròyìn tí yóò ṣiṣẹ́ nílé aṣòfin - NASS

Igbesẹ yii ṣeeṣe ko fa idiwọ fun irina oju ofurufu tori ko ni si oṣiṣẹ ti yoo maa mojuto bo ṣe yẹ ki ohun gbogbo lọ ni papakọ ofurufu.

Awọn ẹgbẹ to gbimọ pọ fẹ gun le iyanṣẹlodi yii ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ irina ofurufu(NUATE), ẹgbẹ awọn ọga lẹnu iṣẹ irina ofurufu (ATSSSAN), ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ ninu iṣ irina ofurufu (ANAP) to fi mọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ atawọn awakọ ofurufu (NAAPE).