India election results 2019: Hema Malini, òṣèré Bollywood n léwájú nínú ìbò India

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Narendra Modi jáwé olúbori lẹẹkan sii ni India

Wọn ti kéde Narendra Modi ti ẹgbẹ oṣelu BJP pé oun lo jawe olubori ni India.

Airwo gee lo gba ẹnu awọn alatilẹyin Modi kaakiri orilẹ-ede India bi wọn ṣe kede esi idibo naa ti wọn ti n ka lati ọsan ọjọ Aiku.

Rahul Gandhi to jẹ olori alatako ẹgbẹ oṣelu Congress to n ba Modi to jawe olubori ni India dupo ti gba fun Ọlọrun.

O sọrọ akin nigba ti o pe ipade awọn oniroyin ni Delhi to si gba pe oun ti padanu ipo ti ẹbi rẹ ti dimu ni Uttar Pradesh ni Amethi lati ọdun 2004.

Oṣere-binrin Hema Malini lo n lewaju

Gbajugbaja oṣerẹ Bollywood, Hema Malini naa lo n lewaju ninu idibo ẹkun ariwa ipinlẹ Uttar Pradesh ni Mathura.

Oṣere-binrin yii ti kopa ninu fiimu agbelewo to le ni aadọjọ sẹyin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Hema n lewaju ninu esi idibo ẹkun ariwa ti wọn ti ka

Hema Malini lo ti kọko bori lọdun 2014 ni eyi to fi wọle ṣoju awọn eniyan ẹkun rẹ bi o ti wuu.

Eto ipolongo idibo rẹ lọdun 2019 yii lo ni kọhun kọọ to pọ ninu nitori pe awọn eniyan bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu bo ṣe n ya fọto bii pe oun n ṣọgbin lori ẹrọ ayelujara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Agogo méje ń lọ lù láàrọ̀ la gbọ́ ariwo ńlá kan'

Bi wọn ṣe n ka eto idibo naa tẹlẹ

Adari ilẹ India láti ọdun 2014, Narendra Modi naa ni o ti n lewaju bayii ninu èsì idibo to ti jade ni orilẹ-ede India.

Odindin ọsẹ mẹfa ni wọn fi dibo yii kaakirir orilẹ-ede India ni eyi ti awọn ajọ eleto idibo ti fẹ ka tan bayii ti Modi si n lewaju ninu esi idibo to ti jade.

Awọn alatako ẹlẹkun jẹkun ni wọn jọ n dije dupo bayii ni India ninu eto idibo naa.

Aago mẹjọ ọjọ Aiku to kọja ti eto idibo naa pari ni wọn ti bẹrẹ si ni ka esi idibo naa lati ẹkun kan si ikeji.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn alatil;ẹyin Modi ni Assam ti wọn ti n yọ ayọ esi idibo silẹ

Ọpọ lo gba pe olori gidi ni Narendra Modi ṣugbọn awọn mii ni o bu epo si ina ẹlẹyamẹya ti ko pọ ni India to bayii tẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!

Awọn alatilẹyin ara Hindu BJP yii lo ti n fidunnu wọn han kaakiri pe awọn ni yoo gbegba oroke.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionContortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí!

Ojọbọ ni wọn n reti Ogbẹni Modi ni olu ile ipolongo ẹgbẹ ni Delhi nibi ti wọn yoo fi adagba eto rọ si ti wọn ba ti jawe olubori tan.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Rahul Gandhi ati Priyanka to jẹ arabinrin rẹ gbọdọ ṣiṣẹ ju ti atẹyinwa lọ

Olori ẹgbẹ alatako fún Modi ni Rahul Gandhi to ni awọn ero lẹyin lẹgbẹ Congress party rẹ.

Egbẹ to ba maa bori lẹyọ kan tabi lafọwọsowọpọ gbọdọ ni ijoko ile mejilelaadọrin o le nigba ninu ọmọ ilé ti wọn jẹ mẹta le logoji o le ni ẹẹdẹgbẹrin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSri Lanka áti India níkan ni irù ològbó yì wá

Lọdun 2014 ni ẹgbẹ BJP bori pẹlu ijoko mejilelọgọrin o le nigba eyi to jẹ ipo to pọ ju ti ẹgbẹ kankan tii ni lati ọgbọn ọdun sẹyin ni India.

Nigba ti ẹgbẹ Congress ni ijoko mẹrinlelogoji pere lọdun 2014

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mamata Banerjee to jẹ minista ẹkun iwọ oorun Bengal naa jẹ alatako gboogi fun Modi

Oludibo miliọnu kan ni ọgọrin eeyan lo ni ẹtọ lati dibo lọdun yii ni India.

Awọn oludije ẹgbẹrun mẹjọ lo n dije fun ipo oriṣiiriṣi ninu ẹgbẹ oṣelu aadọrin le ni ẹgbẹta ni orile-ede India.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn agbẹ ti fẹhonuhan ni ọpọ igba sẹyin lori ohun ti ko tẹ wọn lọrun

Related Topics