Theresa May bú sẹ́kún, ó ní òun kò ṣe olóòtú ìjọba UK mọ́

Theresa May
Àkọlé àwòrán Pẹlu omije ni May fi ṣe ikede rẹ ni adugbo Downing

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May ti kede ọjọ ti yoo kuro lori aga iṣakoso.

May kede ni owurọ ọjọ Ẹti pe oun yoo fi ipo naa silẹ ni ọjọ keje, oṣu Kẹfa, 2019, eyi ti yoo mu ki idije lati yan ẹlomii sipo naa o waye.

Ninu ọrọ to sọ tẹdun-tẹdun, Abilekọ May sọ pe ''oun ti ṣe eyi ti agbara oun ka'' lati ṣe ègbè lẹyin abajade idibo apapọ ilẹ Yuroopu to waye l'ọdun 2016.

Ni adugbo Downing street ni May ti ṣe ikede yii pe ó tó gẹ́,

O digba ti wọn ba yan adari miran sipo ki Theresa May to kogba wọle patapata.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFootballers: ìkà láwọn aṣojú agbábọ̀ọ̀lù míì lágbàyé

Pẹlu omi ẹkun loju ni Theresa May fi ṣe ikede yii ni eyi to fidi aṣayan ọrọ Yoruba mulẹ pe ko si agbara ti ẹnikẹni le sà ju ti ẹni to juni lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí

Related Topics