Oyo NLC mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Àkọlé àwòrán Oyo NLC mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ iyanṣẹlodi alainigbedeke lọjọ Ẹti.

Eyi bẹrẹ lẹyin gbedeke wakati mejidinlaadọta ti wọn fun ijọba lati yanju owo oṣu ti ijọba jẹ wọn ati awọn ọrọ mi i to n jẹ awọn oṣiṣẹ niya.

Ninu atẹjade kan ti awọn akọwe ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ọyọ, Mohammed Ibrahim, fi sita ni Ọjọbọ, ni awọ̀n adari oṣiṣẹ ti paṣẹ fun gbogbo oṣiṣẹ lati joko sile wọn.

Ninu atẹjade naa, ẹgbẹ oṣiṣẹ ni o jẹ nkan to ṣeni laanu pe ijọba ipinlẹ Ọyọ kọwe si ẹgbẹ naa lai wa ojutuu si 'iya to n jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ naa.'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption Niyi Akano,Alaga NUT Oyo lori iyanselodi

Ati pe iyanṣẹlodi naa yoo wa titi ti aṣẹ mi i yoo fi jade.

Image copyright NLC
Àkọlé àwòrán Lati ọdun 2011 ti ijọba to n kuro ni iṣakoso ti de ipo ni oun ẹgbẹ NLC ti jọ n fa awọn ọrọ kan, ti ko si yanju di asiko yii.

Ninu ọrọ to sọ ni olu ile ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ to wa ni adugbo Challenge n'Ibadan, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Bayọ Titilọla-Sodo sọ fun awọn akọroyin lọjọru pe ''ko tọ̀ si ijọba kankan lati maa lo awọn oṣiṣẹ ni ilo ẹrú.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí

Lati ọdun 2011 ti ijọba to n kuro ni iṣakoso ti de ipo ni ati jọ n fa awọn ọrọ kan, ti ko si yanju di asiko yii.

Bakan naa lo sọ pe ko si awawi kankan fun ijọba ipinlẹ lati ma san ẹgbẹrun lọna ọgbọ̀n Naira ti Aarẹ Muhammadu Buhari buwọlu laipẹ yii gẹgẹ bi owo oṣiṣẹ to kere ju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFootballers: ìkà láwọn aṣojú agbábọ̀ọ̀lù míì lágbàyé

Amọ ṣaa, lẹyin ipade kan to waye laarin gbogbo ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọyọ, Akọwe ẹgbẹ NLC ati akọwe igbimọ to n ṣoju ijọba jọ buwọlu atẹjade kan pe ijọba gbọdọ san o kere tan, owo oṣu kan.

Àkọlé àwòrán Oyo NLC mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Owó yii jẹ lara eyi to jẹ awọ̀n oṣiṣẹ ijọba ibilẹ bi i Lagelu, Ẹgbẹda, Ogbomọṣọ North, Ogbomọṣọ South, Surulere, ati Ibadan North West.

Related Topics