Blood donation: Kíni àwọn èrò àti ìgbàgbọ́ tí kò tọ̀nà lórí ẹjẹ́?

ẹni to n fun ni lẹjẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Blood donation: Kíni àwọn èrò àti ìgbàgbọ́ tí kò tọ̀nà lórí ẹjẹ́?

Ajọ WHO ti ilera agbaye ni ẹnikẹni to ba wa ni alaafia lo le fi ẹjẹ silẹ̀.

Ọpọlọpọ lo lé fi ẹjẹ wọn tọrẹ ti ko ba ti si wahala ni agọ ara wọn.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pé ọpọlọpọ itan ati igbagbọ ati arosọ ti ko ni ootọ ninu lo rọ mọ fifi ẹjẹ silẹ lọna ti ko tọna.

BBC ṣagbeyẹwo awọn eyi to wọpọ julọ ninu awọn arosọ naa to jinna si ootọ:

Irọ ni pé àwọn to n jẹ eso ati ẹfọ ko le fi ẹjẹ silẹ

Koko ọrọ to maa n fa ijiroro yii ni lori aṣaraloore to wa ninu ẹjẹ (iron).

Opọ ni ẹru maa n ba pe awọn ti ki jẹ ẹran ati ẹja le ma ni ni eroja aṣaraloore yii to ninu ẹjẹ.

Iwadii ti fi mulẹ pe wọn le fun ẹnikẹni lẹjẹ ti wọn ba ti n jẹun ti eroja aṣaraloore pe sinu ẹ lasiko.

Ati pe ẹnikẹni ti eroja yii ko ba pe ninu ẹjẹ rẹ ko gbọdọ fi ẹjẹ silẹ ni gbogbo agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNjẹ ọ mọ̀ pé mímí afẹ́fẹ́ tí kò dára lè fa àìsàn?

Eyi lo ṣokunfa idanwo ẹjẹ ti wọn kọkọ n ṣe ṣaaju fifi ẹjẹ silẹ ni gbogbo agbaye.

Irọ ni pé to ba ya Tatuu tabi da ara lu ko nile fi ẹjẹ silẹ:

O ṣeeṣe fun ẹni to da ara lu tabi to ya Tatuu sara rẹ lati fi ẹjẹ silẹ.

Ko si ofin to de yiya Tatuu si ara rẹ ṣugbọn o ni gbendeke asiko ti o gbọdọ fi duro koo to le fi ẹjẹ silẹ.

Ajọ ilera agbaye WHO ni ki iru ẹni bẹe duro fun oṣu mẹfa lẹyin ti o ya Tatuu, wakati mejila lẹyin ti o da ara rẹ lu yii ki o to le fi ẹjẹ silẹ.

Ti o ba ṣiṣẹ abẹ ẹnu, o gbọdọ duro fun odindin ọjọ kan ki o to le fi ẹjẹ silẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko si ofin to de yiya Tatuu si ara rẹ ṣugbọn o ni gbendeke asiko ti o gbọdọ fi duro koo to le fi ẹjẹ silẹ.

Ṣé lootọ ni pe alaboyun, alaarẹ, ọmọde tabi arugbo ko le fi ẹjẹ silẹ?

Bẹẹni, OOTỌ ni eyi, alaboyun, alaarẹ, ọmọde, àti arugbo ko le fi ẹjẹ silẹ̀.

Àwọn ti wọn ti ni arun kogboogun HIV, Hepatitis, arun ibalopọ Syphilis, tabi ikọ́ ife ati awọn ajakalẹ arun to n ràn lati ara ẹni kan si ikeji ko le fi ẹjẹ silẹ.

Ẹnikẹni to ba ti ni apẹrẹ iba, ọfinkin, inu rirun ati ọfun didun gbọdọ sinmi fun ọjọ mẹrinla ko to le fi ẹjẹ silẹ.

koda awọn to ba ṣẹṣẹ lo oogun apa kokoro ara tan gbọdọ duro fun ọjọ meje ki wọn fi sinmi ki wọn to le fi ẹjẹ silẹ.

Ofin to rọ mọ gbendeke fifi ẹjẹ silẹ lẹyin itọju aisan kan yatọ sira wọn lati orilẹ-ede kan si ikeji lagbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌdíje ata tútù: Jẹ ata 50, ko gba góólù gírámù mẹ́ta

Alaboyun, abiyamọ to n fọmọ lọyan lọwọ, tabi to ṣẹṣẹ ṣẹyun gbọdọ sinmi daadaa ko to le fẹjẹ silẹ.

Ẹni to n ṣe nkan oṣù lè fi ẹjẹ silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionafin pupa

Ẹni to ba ti pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun, o keere tan, lo le fi ẹjẹ silẹ nitori ofin to rọ mọ igbesẹ naa.

Ṣugbọn ko si ọdun ti eeyan ko ṣi le fi ẹjẹ silẹ bo tilẹ jẹ pe awọn orilẹ-ede kan ni ọdun ọgọta si aadọrin ni tiwọn.

Afiyesi maa n wa fun awọn ti wọn n fẹjẹ silẹ̀ fún ìgbà akọkọ ki wọn le ni oye to yẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ofin wa fun awọn akọsiakọ to ba fẹ fi ẹjẹ silẹ

"Awọn igbesẹ to léwu"

Igbe aye ẹda kun fun ewu ninu eyi to le ma jẹ ki o rọrun fun eeyan lati fi ẹjẹ silẹ ni asiko kan.

Ajọ WHO ni o ṣeeṣe ki awọn to n ni ibalopọ pẹlu ẹni pupọ, tabi awọn aṣẹwo tabi awọn to n ni ibalopọ akọ si akọ.

Ẹni to ba ni aisan Iba, Dengue ati Zika ko gbọdọ fi ẹjẹ silẹ.

Ọpọlọpọ orilẹ-ede fofin de awọn ti fifi ẹjẹ wọn silẹ lewu pupọ.

Wo odiwọn ẹjẹ ara re:

Pupọ ninu eeyan adarihurun maa n saaba ni ẹjẹ jálá lita marun un ni agọ ara wọn.

Ida ẹẹdẹgbẹta mili-lita ni jala ẹjẹ ti wọn maa n saba fa ni ara.

Laarin ọjọ kan si meji ni ara fi maa n da irufẹ ẹjẹ yii pada si ara lẹyin too ba ti fi ẹjẹ silẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fifi ẹjẹ silẹ maa n jẹ ohun ayọ pe o le gba ẹlomii silẹ

Ni ipari:

Bi o ṣe lagbara naa ni o ni ilera lati fi ẹjẹ silẹ.

Iwọn rẹ ko gbọdọ din ni aadọta kilo bẹẹ ko gbọdọ ju ọgọjọ kilo lọ.

Ọjọ ori rẹ gbọdọ jẹ laarin mejidinlogun si mẹrindinlaadọrin (O nii fi ṣe ofin agbegbe kọọkan).

Oloyun ati ẹni to n fọmọ lọyan ko le fi ẹjẹ silẹ.

O ko gbọdọ ni arun kogboogun.

O ko gbọdọ ti ṣe nkan to lewu ni oṣu mejila sẹyin.

Fifi ẹjẹ silẹ maa n doola ẹmi

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí