Inú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà -Idowu Akinbole
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Blood Donor Day: Láìsí ẹ̀jẹ̀ kò sí ẹ̀mí

O dára láti máa fi ẹjẹ silẹ fún ilera ara rẹ - Idowu

Opọlọpọ eniyan ni wọn ko ni oye to kun to lori pataki fifi ẹjẹ silẹ.

Ogbẹni Akinbole Idowu to je igbakeji adari ajọ to n mojuto ẹjẹ gbigba ni ipinlẹ Eko ṣalaye kikun fun BBC lori idi to fi yẹ ki eeyan maa fi ẹjẹ silẹ.

O mẹnuba ipa ti ẹjẹ tuntun n ko ni agọ ara ni eyi to ṣeeṣe fun enikeni to ba n fi ẹjẹ silẹ loorekoore.

Wo pataki igbesẹ to yẹ ni gbigbe koo too fi ẹjẹ rẹ silẹ Àròsọ àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn lórí gbígba ẹ̀jẹ̀

Awọn miran to wa ni ibudo ẹjẹ gbigba yii naa sọrọ lori idi ti awọn ṣe jade wa fi ẹjẹ silẹ fun BBC.