India: Idán yíwọ, Chanchal Lahiri kú sómi gbe

Chanchan Lahiri
Àkọlé àwòrán Chanchan Lahiri

Apidan India kan ti wọ́n gbe ju sinu odo pẹlu ṣẹ́kẹ́ ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ pẹlu ero lati lefo pada lori omi ti gba ibẹ ku.

Awọn ọlọpaa lo fi aridaju han pe Chanchal Lahiri ko ye e.

Idan naa ni wọn pe ni Houdini eyi tii ṣe idan kan to gbayi ju lagbaye ti gbajugbaja apidan Harry Hudini ti ṣe ri l'oun naa fẹ tun ṣe.

Apidan ọmọ India yii lo n gbiyanju lati tun ọgbọn Harry Houdini dá, lọ̀rọ̀ bá yiwọ!

Chanchai Lahiri jẹ gbajugbaja ọlọwọ idán ọmọ India to ti n pidan lati ọdun to ti pẹ.

O gbiyanju lati tun idan naa ṣe nipa bibẹ sinu odo lẹyin ti wọn ti soo pẹlu ẹ̀wọ̀n tan.

Gbogbo àwọn oluworan ti wọn wa wo idan naa rii nigba ti o bẹ sinu odo naa ṣugbọn wọn ko rii ko jade.

Orukọ miran ti ọlọwọ idan yii n jẹ ni Mandrake.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSri Lanka áti India níkan ni irù ològbó yì wá

O sọkalẹ oke odo naa pẹlu ọkọ oju omi ko to wa bẹ sinu odo naa to ti dawati di asiko yii.

Agadagodo mẹfa ati ẹwon lo fi so ara rẹ ni odo Hooghly ki wọn to maa waa ni odo ni West Bengal.

Kí ló yẹ ká se sí ẹkùn tó pa ènìyàn márùń?

Awọn agbofinro, awọn omuwẹ ṣi n gbiyanju lati wa Apidan naa pẹlu awọn onworan to rii nigba to bẹ sodo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHakeem: Mo lè sọ arúgbó dí ọmọge nígbà tó bá wù mí

Ọkan lara awọn to ri Mandrake nigba to bẹ sinu odo naa, Jayanta Shaw to jẹ ayaworan sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Shaw sọ fun BBC pe oun ba Apidan naa sọrọ ko too bẹ sodo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Owó tí mo ń rí lórí Garri ni mo fi ń ran ọkọ lọ́wọ́'

O ni oun beere idi ti Lahiri ṣe fẹ fẹmi ara rẹ wéwu nipa idán ṣiṣe.

Ibeere yi ni Lahiri fi ẹrin dahun pe: Ti mo ba ṣe é to ba di odindin, o di idán ni yẹn; ṣugbọn ti ko ba jọ ara wọn, a jẹ pe aṣiṣe ni ni yẹn to dẹ le mu ewu dani.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÉégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o!

O ni Lahiri ni oun fẹ pidan yii wo ki ọkan awọn onworan le fà si iṣẹ ọlọwọ idan pada ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionChef Adefunkẹ: Òórùn ewé tí wọ́n n pọ́n ìrẹsì ọ̀fadà si jẹ́ adùn lọ́tọ̀

Iriri Ọlọwọ idan tẹlẹ:

Wọn ni eyi kọ ni igba akọkọ ti Mandrake ọlọwọ idan ti maa n ko somi pidan rẹ tẹlẹ.

O ti figba kan ko sinu odo yii kan naa ni nkan bii ogun ọdun sẹyin.

Inu apoti gilaasi lo fi ara rẹ si ko too ko sodo naa ni eyi ti ori koo yọ pẹlu ariwo nla lasiko ọhun.

Ayaworan Shaw sọ fun BBC die lara awọn iṣe idan ti Mandrake ti ṣe ninu odo ti o ṣoju oun tẹlẹ.

O ni oun ko figba kankan ro pe Mandrake ko ni jade ninu odo naa lọtẹ yii.

Awọn agbofinro orilẹ-ede India ni awọn ko tii le kede pe ọlọwọ idan yii ti ku laijẹ pe wọn ri oku rẹ yọ ninu odo to wọ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja