PDP: Ilé aṣòfin àti Gómìnà Kwara kùnà pẹlú yíyọ àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀

Aworan Gomina Kwara ati ami idanimọ ẹgbẹ PDP Image copyright officialpdpnig/RealAARahman

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí tápà sí ìgbésẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara nípa jíjà ìwé lọ gbélé rẹ fawọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.

Gẹgẹ bí ohùn tí alága ẹgbẹ́ náà Kola Shittu sọ nínú atẹjade kàn, o ní ìgbésẹ yí lòdì sí òfin àti pé kò tọ́ kí ilé aṣòfin daba yíyọ àwọn alága náà lópin ìgbà tí wọn kò tí ṣé iwadi tó péye.

Kola Shittu ní ìdájọ ilé ẹjọ kàn sí wà n'ilẹ eléyìí tó fòfin dè èyíkéyìí Gómìnà tó bá fẹ yọ àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tàbí jáwé lọ rọọkun nílé fún wọ́n.

Ẹgbẹ náà wà rọ gbogbo àwọn èèyàn Kwara láti má ṣé kọbi ará sí ìgbésẹ yìí nítorí pé àwọn alága náà ṣì ní aṣojú ará ìlú tí wọn dibo yan.

Kí ló mú Gómìnà lè àwọn alága lọ sílé

Lọ́jọ́ ìṣẹgun ní Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara,Abdulrahman Abdulrazaq fún gbogbo àwọn alága ijọba ìbílẹ̀ Mẹ́rẹ̀rìndínlógun àti àwọn ìgbimọ míràn, ni ìwé lọ gbé ile rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi abá ti àwọn ọmọ ile ìgbìmọ aṣofin dá.

"Ní ìlànà abá àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ aṣòfin ní ọjọ kejidinlogun oṣu kẹfa, emi Abdurahaman Abdulrazaq to jẹ gomina ipinlẹ Kwara ti dá gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ mẹrẹrindinlogun duro lẹnu iṣẹ́ wọn fún oṣù mẹ́fà tabi titi èyìn àbájade ìwádìí ìwà jẹgudujẹra ti awọ́n ọmọ ilé ìgbìmọ ìpínlẹ̀ Kawara fi kan wọ́n."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIná Ibadan: Gbogbo dúkìá tó wà lókè ilé alájà kan náà ló jóná tán

Idáduro awọn alága ìjọba ìbílẹ̀ yìí wáye lẹ́yin wákati díẹ ti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ aṣòfin dábàá pe ki wọ́n da wọ́n duro.

Ní ìlànà ìwé ofin olrilẹ̀-èdè Nàìjíríà tọdun 2006, o fún gómìnà ni agbára áti dá àwọn alaga ìjọba ìbilẹ̀ dúró fún oṣù mẹ́fà.

Bákan náa ní òfin gbá ilé ìgbìmọ asofin láàye láti wádìí àwọn alaga ijoba ibilé tí ìwà jégujdujẹra ba wáye láàrin wọ́n.