Tory leadership: Àwọn olùdíje náà ni Boris Johnson, Michael Gove àti Jeremy

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsofin Boris Johnson lo wa loke tente, ti Micheal Gove ati Jeremy si tẹle lọwọọwọ ninu idibo si ipo Olotu Ilẹ Gẹẹsi.

Awọn mẹta lo ku to n dije dupo fun Olotu Ijọba ilẹ Gẹẹsi, lẹyin ti Theresa May fi ipo silẹ.

Asofin Boris Johnson lo wa loke tente, ti Micheal Gove ati Jeremy si tẹle lọwọọwọ, lẹyin ti Sajid Javid kuna nitori oun lo ni ibo to kere ju ninu idibo abẹnu to waye.

Boris Johnson ni ibo 157, Micheal Gove ni 61, nigba ti Jeremy Hunt si ni ibo 59.

Idibo ẹlẹẹkarun yoo waye ni oni laago mẹta abọ ọsan (15:30 BST) si aago marun un abọ (17:30). Ibẹ ni wọn yoo ti mu awọn meji to se daradara julọ.

Ọjọ Kejilelogun, Osu Keje ọdun 2019, ni wọn yoo ma a kede ẹni to jawe olubori ninu idibo.