Global Vaccine crisis: Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú abẹ́rẹ́ àjẹsára ń di òkú l'ágbáyé!

vaccine Image copyright Getty Images

Pẹlu bi awujọ agbaye ko ṣe ni ifọkantan to jọju ninu elo abẹrẹ ajẹsara, o daju pe ina igbogun ti awọn aisan kaisan lawujọ yoo jo ajorẹyin ni, gẹgẹ bii awọn onimọ ti ṣe kilọ.

Iwadi ijinlẹ kan to waye lori iha tawọn eeyan lagbaye n kọ si abẹrẹ ajẹsara fihan pe, igbẹkẹle wọn ninu rẹ ti lọ silẹ pupọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajọ The Wellcome Trust to ṣe iwadii naa jẹ ko di mimọ pe, ẹgbẹrun lọna ogoje eeyan kaakiri awọn orilẹede ogoje lagbaye, ni wọn ṣe iwadii naa fun.

Eyi si n waye pẹlu bi ajọ eleto ilera lagbaye, WHO ti ṣe kede didẹyẹsi abẹrẹ ajẹsara, gẹgẹ bii ọkan gboogi lara ohun mẹwa to n ti igi bọ oju eto ilera lagbaye.

O nilo itakun iwadii ti igbalode (pẹlu atilẹyin JavaScript) lati wo ibi yii

Iwadi agbaye naa fihan pe, ọpọ awọn eeyan lo ṣalaye pe igbẹkẹle diẹ lawọn ni ninu abẹrẹ ajẹsara.

Nigba ti wọn bi wọn boya ajẹsara dara:

  • Ida mọkandinlọgọrin ninu ọgọrun, (79%), lo fara mọọ.
  • Ida meje ninu ọgọrun, (7%) ko fara mọọ
  • Ida mẹrinla ninu ọgọrun (14%) ko tilẹ fi sibikan.

Nigba ti wọn bi wọn boya wọn gbagbọ pe ajẹsara n ṣiṣẹ:

  • Ida mẹrinlelọgọrin (84%) gba
  • Ida marun (5%) ko gba
  • Ida mejila (12%) ko fi si ibi kan
Image copyright Science Photo Library
Àkọlé àwòrán Arun ẹyi lee mu ẹmi lọ

Ki ni eyi tumọ sii?

Abẹrẹ ajẹrẹsara lo n daabo bo ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan kaakiri agbaye. Wọn ti pa aisan olode tabi ṣanpọnna, (Small pox) run, ti o si ti n mu iparun awọn aisan miran bii rọmọlapa-rọmọlẹsẹ sun mọ etile.

Ṣugbọn awọn aisan miran bii igbona (Measles) ti n pada yọju saye, ti awọn onimọ si n fọnrere rẹ pe, awọn eeyan n yẹra fun abẹrẹ ajẹsara to lee dena irufẹ awọn arun yii, nitori ibẹru ati aṣigbọ.

Dokita Ann Lindstrand, to jẹ onimọ agba fun ajọ ilera agbaye, WHO ṣalaye pe, ibi ti ọrọ de duro bayii le pupọ.

Image copyright Getty Images

Igbona ti pada wa

Awọn orilẹede ti wọn ti n sunmọ ati pa arun igbona run ni wọn tun ti n ri ọwọja arun naa bayii.

Akọsilẹ n fihan pe, gbogbo ẹkunjẹkun lagbaye lo ti n ri ọwọja arun yii bayii, eyi ti o tilẹ tun ti peleke sii pẹlu ida ọgbọn ninu ọgọrun laarin ọdun 2016 si 2017.

Amọṣa, igbesẹ ati kọ ipakọ si abẹrẹ ajẹsara lewu fun awọn to ba ni arun yii ati awujọ wọn.

Bi awọn eeyan ba gba abẹrẹ ajẹsara, yoo dẹkun arun yii, ki o to ran ka gbogbo awọn eeyan to n gbe lagbegbe naa.

Image copyright Getty Images

Ki lo n fa ina igbẹkẹle ninu abẹrẹ ajẹsara to n jo ajorẹyin?

Lara awọn idi ti igbẹkẹle awọn eeyan fi n lọ silẹ ni bi ọwọja aisan bẹẹ ba ti lọlẹ; ọpọ eeyan ni kii ri idi kan pato ti wọn fi lee gba a.

Bakan naa ni awọn iṣoro miran to n waye nipa lilo awọn ajẹsara naa, lo n faa ti ọpọ fi n sare jina si abẹrẹ ajẹsara.