Body Farms: Ṣé ó tọ̀nà láti fi ojú òkú ráre báyìí?

Ẹran ara oku to wa ninu ago onirin, ti wọn gbe silẹ ni oko oku
Àkọlé àwòrán Awọn oku ti wọn fi ago onirin daabo bo lọwọ igun ajoku

Ikilọ: Iroyin ti ẹ fẹ ka yii ni agbara pupọ, aworan ibẹ si lee ma wu oju ri.

Ti eeyan ba n wo oko oku yii lati ọkankan, o dabi ori koriko ti eeyan ti lee rin lati naju, sugbọn awọn koriko ibẹ lọra daada, nitori ara oku ti wọn fi n se ounjẹ lati ọsẹ diẹ sẹyin.

Amọ bi eeyan ba se n rin lọ ninu oko yii, ni oorun awọn oku to wa nilẹ yoo gba imu eeyan kan, eyi to lee mu omije jade pe se awọn eeyan kan lo n rare bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oko yii ju eeka ilẹ kan lọ, ti awọn oku to to mẹẹdogun si na silẹ gbọọrọ lai si asọ ni ara wọn, koda, wọn gbe awọn miran sinu ago onirin tabi onike, tawọn miran si wa ninu saare ti ko jin rara, amọ gbogbo wọn ni wọn n fi ara gba awọn eroja sayẹnsi kan.

Oko oku naa, ti wọn da silẹ lọdun 2017, jẹ ti awọn onimọ sayẹnsi lati ileẹkọ fasiti South Florida, to n se iwadi lori ohun ti yoo sẹlẹ si oku lẹyin to ba jade laye, ti ọgba ileẹkọ naa si sunmọ ọgba ẹwọn kan.

Àkọlé àwòrán Ti oku ba ti jẹra, o maa n ni ipa lori ayika to ba wa

Sugbọn ohun ti wọn n fi oju awọn oku to wa ni oko oku yii ri kọja afẹnusọ, to si yatọ si itọju ti a maa n fun oku. Irufẹ oko oku bayi si to mẹfa ọtọtọ to wa nilẹ Amẹrika, tawọn orilẹede bii Australia, Canada ati UK naa si n gbero lati ni oko oku ti wọn naa.

Ọpọ oku ti wọn tẹ silẹ ni oko oku yii ni awọn oku funra wọn ti fi ara wọn silẹ, ki wọn to ku tabi tawọn ẹbi wọn fi oku wọn tọrẹ fun oko naa.

Image copyright IFAAS/USF
Àkọlé àwòrán Awọn onimọ sayẹnsi n se akọsilẹ ti yoo wulo lọjọ iwaju ti wọn ba n se iwadi nipa iwa ipaniyan

Afojusun dida oko naa silẹ ni lati mọ bi oku se n jẹra ati ohun to n sẹlẹ si ayika ti iru oku bẹẹ ba wa. Bakan naa ni wọn n se akojọpọ awọn akọsilẹ to se pataki lati ipasẹ isẹ iwadi yii, eyi ti yoo seranwọ lati wa ojutu si awọn iwa ọdaran loniranran, ti agbega yoo si ba ọna ti wọn n gba se idamọ ẹda kọọkan.

Ọpọ eeyan ni iru isẹ bayi maa n ba lẹru, eyi to ni se pẹlu fifi ọwọ kan oku ati sise akọsilẹ nipa ohun to n waye pẹlu oku to n jẹra ni isẹju isẹju

Àkọlé àwòrán Awọn onisẹ iwadi kan n fajuro lori agbekalẹ oko oku

Bi o tilẹ jẹ pe anfaani nla ni yoo ba iran ọmọniyan lọjọ iwaju lati ipasẹ isẹ iwadi yii, amọ ibeere ton gba ọkan awọn eeyan kan ni pe, se o yẹ ki oku maa rare nitori isẹ iwadi bi eyi?

Àkọlé àwòrán Awọn ẹya ara kan n jẹra