Èyí ni ìdí tí àwọn obìnrin kan to n ṣe nkan oṣù fi n yọ ilé ọmọ wọn kúrò ní India

Aworan nkan oṣu Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Oju buruku ni wọn fi maa n wo awọn obinrin to ba n ṣe nkan oṣu ni India

Abọ iwadii kan lori ọrọ awọn obinrin to n ṣiṣẹ, to si n ṣe nkan oṣu ti jade lati India.

Iroyin naa si jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ.

Lati aimọye ọdun, nkan eewọ ni wọn ka nkan oṣu obinrin si ni orilẹ-ede naa, igbagbọ wọn ni pe awọn obinrin to ba n ṣe nkan oṣu ko mọ, wọn ki i si jẹ ki wọn o kopa ninu ayẹyẹ ati ọrọ ẹsin.

Ṣugbọn lasiko yii, awọn obinrin to kawe to si n gbe ni awọn ilu nla ti bẹrẹ si ni kọju ija si aṣa naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCerebral Palsy: àrùn tó n gba omijé lójú ẹni láìnídìí

Kinni iwadii na sọ?

Iwadii fihan pe ọpọlọpọ ẹgbẹrun awọn ọdọmọbinrin lo ti ṣe iṣẹ abẹ lati yọ ile ọmọ wọn kuro ni ipinlẹ Maharashtra laarin ọdun mẹta pere.

Awọn obinrin kan ṣe bẹ ẹ ki wọn o le ri iṣẹ ṣe ni oko ireke.

Lọdọọdun, ọpọlọpọ awọn idile to talika lati agbegbe Beed, Osmanabad, Sangli ati Solapur maa n rinrinajo lọ si awọn agbegbe awọn olowo lati ṣiṣẹ ni oko ireke fun oṣu mẹfa.

Nibẹ si ni awọn agbanisiṣẹ ti maa n wa gbogbo ọna lati yan awọn idile naa jẹ.

Awọn agbanisiṣẹ naa kii fẹ ẹ gba awọn obinrin, nitori pe iṣẹ agbara ni ireke gige, ati nitori pe awọn obinrin si maa n pa iṣẹ jẹ lasiko ti wọn ba n ṣe nkan oṣu wọn.

Obinrin to ba si ti pa iṣẹ jẹ yoo san owo itanran. Eyi lo mu ki ọpọ obinrin ti ko kawe lati maa gbe igbesẹ to l'ewu fun ilera ati aye wọn.

Igbeaye ni oko ireke ko dara rara; inu ahere ti ko ni ile iyagbẹ ni awọn idile naa maa n gbe nitosi oko ti wọn ba ti n ṣiṣẹ.

Bi agbegbe naa ṣe dọti maa n fa aarun oriṣiriṣi fun awọn obinrin.

Awọn ajafẹtọ tilẹ sọ pe awọn dokita oniwa ibajẹ maa n gba awọn obinrin naa ni imọran lati ṣe iṣẹ abẹ, koda ko jẹ pe aisan kekere ti oogun le wosan ni awọn obinrin naa gbe lọ sileewosan.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ obinrin maa n ṣiṣẹ olukore ni oko ireke ni India

Nitori pe ọpọ obinrin ni agbegbe naa lo n lọ sile ọkọ lọmọde, ọpọ wọn si ti bi ọmọ bi i meji si mẹta ki wọn o to pe ọdun mẹẹdọgbọn, ati nitori pe awọn dokita kii ṣọ iṣoro ti wọn yoo koju ti wọn ba gbe ile ọmọ wọn jade, pupọ wọn gbagbọ pe ko buru ti awọn ba yọ ọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àjẹ́, eégún, kí ni wọn ò pè mí tán tórí Vitiligo lára mi'

Eyi ti mu ki ọpọlọpọ abule ni agbegbe naa o di "abule awọn obinrin ti ko ni ile ọmọ''.

Amọ iwadii fihan pe kii ṣe gbogbo wọn lo maa n ṣiṣẹ ni oko ireke.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsa Trokosi nibi ti ọmọde ti n jiyan ẹsẹ mọlẹbi rẹ , wọpọ ni Ghana, Togo ati Benin.

Bakan naa ni Minisita fun eto ilera ni Maharashtra, Eknath Shinde, fidirẹmulẹ pe awọn obinrin to to ẹgbẹrun mẹrin le ẹgbẹta ati marun un, 4,605, lo ti yọ ile ọmọ wọn kuro.

Ati wi pe iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ naa.

Iṣoro to n doju kọ awọn obinrin to ti yọ ile ọmọ wọn kuro

Iwadii akọroyin BBC to ṣe abẹwo si abule Vanjarwadi to wa ni agbegbe Beed, fihan pe ilaji awọn obinrin to wa ni abule naa lo ti yọ ile ọmọ wọn kuro.

Ọpọ awọn obinrin to si fi ọrọ wa lẹnuwo sọ pe awọn ko ni ilera pipe lati igba ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYaa Asantewaa: Ti ẹyin ọkunrin Ashanti kò bá tẹsiwaju, awa obinrin yóò lọ

Irora ni ẹyin, ọrun ati orunkun, to fi mọ ọwọ, ẹsẹ ati oju wiwu ni obinrin kan sọ pe o maa n ṣe oun.

Obinrin miran sọ pe 'ooyi lo maa n kọ oun nigba gbogbo, ti oun ko si le rin daadaa'.

Nitori eyi, awọn obinrin mejeeji sọ pe awọn ko le ṣiṣẹ ni oko ireke mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'IBB da Abiola lẹ́yìn tó búra pẹ̀lú Quran'