Donald Trump: Àwọn obìnrin ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Amẹrika fọnmú sí ọ̀rọ̀ Trump

Àkọlé àwòrán Àwọn obìnrin ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Amẹrika fọnmú sí ọ̀rọ̀ Trump

Awọn obinrin aṣojuṣofin ti aarẹ Donald Trump sọrọ nipa wọn lori ayelujara ni ọrọ rẹ ko dun awọn.

Awọn aṣojuṣofin alawọ dudu mẹrin naa, Alexandria Ocasio-Cortez, Ilhan Omar, Ayanna Pressley ati Rashida Tlaib ti parọwa fawọn eniyan pe eyi ko di awọn lọwọ iṣẹ.

Wọn ni àmọ́ ni ọrọ Aarẹ Donald Trump, ko mọ ara ẹran rara.

Ṣaaju ni aarẹ Trump ti fi sita loju opo twitter rẹ pe awọn obinrin mẹrẹerin "le maa lọ".

Aarẹ Donald Trump to n tukọ Amerika ti sọrọ ni kikun lori ohun to ṣo lori ayelujara pe ko ri bi wọn ṣe n gba a.

Trump ni oun kii ṣe ẹlẹyamẹya rara ti ko nifẹ ọmọlakeji rẹ lati iran tabi to ni aawọ miran.

Orọ aarẹ Trump to kọkọ fi sita lọjọ Aiku ko pe orukọ awọn obinrin mẹrẹẹrin yii rara ṣugbọn awọn eniyan gba pe ti olówe ni òwe ni.

Aarẹ Trump ni awọn obinrin naa wa lati orilẹ-ede ti ko lojutuu ati pe ki wọn pada sile.

Wọn bi mẹta ninu awọn obinrin naa is Amerika nigba ti Omar wa lati Somalia lati kekere.

Awọn obinrin mẹrẹẹrin ti fesi pe àwọn yoo gbajumọ ọrọ oṣelu to ṣe koko ju ọrọ ti ko ba ara ẹran ti Trump n sọ lọ.

Arabinrin Omar ati Tlaib tun tẹnumọ ọ pe ki wọn yọ aarẹ Donald Trump kuro nipo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn ọdọ Ondo fẹ̀họ́nù hàn lórí ìṣekúpani Funke Olakunrin