Olólùfẹ́ méjì jábọ́ láti àjà kẹsàn án lásìkò tí wọ́n n ṣe kerewà

Image copyright Getty Images

Obinrin kan ti ku iku ojiji lẹyin to jabọ lati aja kẹsan ile kan lasiko ti oun ati ololufẹ rẹ n ṣe kerewa, ṣugbọn ololufẹ rẹ ọhun ye.

Iwe iroyin Daily Mail gbe e pe wọn ri oku obinrin naa to jẹ ẹni ọgbọn ọdun, ni isalẹ ile ọhun to wa ni ilu St Petersburg l'orilẹede Russia, lalẹ ọjọ karun un, oṣu Keje lasiko ti ariya kan ti awọn araadugbo sọ pe o larinrin pupọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣ'oju wọn sọ pe tẹlifisan ni awọn kọkọ ri to fo jade lati oju ferese ibugbe naa, lẹyin naa ni obinrin ọhun ati ololufẹ rẹ to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọnfo jade lati oju ferese bọ si isalẹ ile.

'Àṣírí ọkọ mi tú sími lọ́wọ́, ṣé mo le dáríjì í?'

'Ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ mi ńpaná iṣẹ́ mọ́ mi lára'

"Àlùfàá méjì wà lára àwọn mẹ́rin tó fi ipá bámilòpọ̀"

Àwọn ọ̀nà tí obìnrin fi le gbádùn ìbálòpọ̀

Awọn oniroyin l'abẹle sọ pe oju ẹsẹ ni obinrin naa ku nitori pe ori lo kọkọ fi gba ilẹ, ṣugbọn ọkunrin naa ye nitori pe bo ṣe jabọ ni tiẹ, ori obinrin naa lo jabọ le ati koriko to wa ni tosi.

Bakan naa ni awọn kan sọ pe ọkunrin naa ti ko fẹ ẹ si aṣọ ni ara arẹ dide, o si pada si ibi ariya naa.

Botilẹjẹ pe awọn iroyin to kọkọ jade sọ pe tẹlifisan to jabọ lo pa obinrin naa, awọn aworan ti wọn ya nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye fihan pe ko si aṣọ kankan ni ara a rẹ lati ibara idi si isalẹ.

Lẹyin ti wọn fi ọrọ wa awọn ti ọrọ ṣ'oju wọn lẹnu wo, awọn ọlọpaa fidirẹmulẹ pe niṣe ni awọn ololufẹ naa n ba ara wọn lopọ lori ferese naa nigba ti wọn jabọ.

Botilẹjẹ pe awọn ọkunrin meji mi i wa ninu ile naa nigba ti ijamba yii waye, wọn ko fi ẹsun kan wọn.

Ijọba si ti bẹrẹ iwadii iṣẹlẹ naa.